Agbara mi ko gbe wahala ipo aarẹ daadaa mọ, mo n rọju ni- Buhari

Faith Adebọla

 Olori orileede wa, Ajagun-fẹyinti Muhammadu Buhari, ti ṣalaye pe ko rọrun foun lọjọ ori oun lati maa kopa ninu igbokegbodo iṣẹ gẹgẹ bii aarẹ orileede, o ni ara oun ti di ara agba, niṣe lo n ṣe oun bii ki oṣu mẹtadinlogun to ṣẹku yii tete de, koun le sinmi bo ṣe yẹ.

Buhari la ọrọ yii mọlẹ nigba ti wọn n fọrọ wa a lẹnu wo lori eto tẹlifiṣan ijọba apapọ NTA, l’Ọjọbọ, Tọsidee, ọsẹ yii.

Ṣe lọjọ kẹtadinlogun, oṣu kejila, ọdun to kọja, ni Buhari pe ọdun mọkandinlọgọrin (79) loke eepẹ, toun atiyawo ẹ, pẹlu awọn lọgaa lọgaa lẹnu iṣẹ ọba kan si lọọ ṣayẹyẹ ọjọọbi naa niluu Instanbul, lorileede Turkey.

Ninu ọrọ rẹ lori tẹlifiṣan NTA, Buhari ni: “Nipa ti ọjọ ori mi, mo maa n ri awọn ojugba mi, niṣe ni wọn n sinmi lasiko yii, ẹ ma jẹ ki n tan yin, niṣe lo n ṣe mi bii ki oṣu mẹtadinlogun to ku yii tete de, kọwọ emi naa le dilẹ diẹ.

“Ara ti di ara agba, keeyan ṣi maa ṣiṣẹ ọfiisi fun wakati mẹfa, meje, tabi mẹjọ loojọ ki i ṣọrọ apara, ki n too mojuto awọn ipade ati ijiroro igbimọ apaṣẹ lọṣọọsẹ, ki n too fesi si awọn lẹta to n wọle lati awọn ipinlẹ gbogbo, iṣẹ nla ni.

“Iṣẹ nla gidi ni o, ṣugbọn emi ni mo wa a, tori ẹ ni mi o fi le ṣaroye. Mo ti jẹ gomina ri, mo ti wa nipo minisita, saa keji si ni mo n lo lọ yii gẹgẹ bii aarẹ, o ti mọ mi lara, ki lo tun ku ki n ṣe forileede yii? Mo ti ṣe gbogbo nnkan ti agbara mi gbe, ireti mi ni pe ti mo ba lọ, awọn ọmọ Naijiria maa boju wẹyin wo awọn nnkan ti mo ti ṣe, wọn aa si kan saara si mi.

“Ohun ti mo reti kawọn ọmọ Naijiria sọ nipa mi ni pe ‘ọkunrin yii gbiyanju gbogbo agbara ẹ o.’ Mo maa jẹ ki aabo wa ni Naijiria ju bo ṣe ri yii lọ, ki n too kuro. Mo fẹ kawọn ọmọ Naijiria yin mi ni.”

Leave a Reply