Agbara ojo wọ kẹkẹ Maruwa atawọn ero inu ẹ lọ 

Monisọla Saka

Pẹlu bi ojo ṣe n fojoojumọ ya yii lai dawọ duro nipinlẹ Eko, lati bii ọjọ mẹta, akunfaya ti oju popo atawọn gọta nla n kun ti ṣokunfa bawọn eeyan kan ṣe padanu ẹmi wọn l’Ọjọbọ, Tọsidee, ọjọ karundinlogun, oṣu Kẹfa, ọdun yii.

Ninu fidio ti obinrin kan gbe sori Instagraamu rẹ lo ti n sọ pẹlu omije loju pe ki Gomina ipinlẹ Eko, Babajide Sanwo-Olu, lati ba wọn wa nnkan ṣe si ọrọ omiyale lagbegbe naa.

O ni, “Gomina Sanwo-Olu, ẹ jọọ, ẹ ṣaanu wa, ẹ ṣaanu awọn eeyan agbegbe yii. Ẹyin naa ẹ wo bi omi ṣe n ṣe yaayaaya, awọn eeyan o le jade. Awọn to wa lapa odi keji o le wa si apa ibi. Loju mi nisinsinyii bayii ni omi fi gbe awọn eeyan lọ. Ninu mọto ti mo wa nibi, loju mi bayii, ni omi yii ṣe gbe odidi kẹkẹ Maruwa kan lọ pẹlu ero inu ẹ.

Bo ṣe di pe o mẹnu le ọrọ ọmọdebinrin tomi gbe lọ yẹn lo bu sẹkun.

“Ọmọbinrin kekere kan kọja lara mi laipẹ yii, bẹẹ ọmọ to ni ipenija ni o. Omi ti gbe ọmọ yẹn lọ. Mi o mọ ẹni to ran iru ọmọ yẹn niṣẹ niru akoko bẹẹ. Ki n ti mọ ki n da a duro o. Aaaah! Nibi agbegbe Abattoir, ni Agege, yẹn ni o, omi kanaali nla yẹn ni. Bo ṣe maa n ṣẹlẹ lọdọọdun ree mọ agbegbe Abule-Ẹgba. Ẹyin naa ẹ wo o, ọna apa ibi yii ni omi yii gbe ọmọ yẹn lọ.

“Agege ni mo dagba si. Ẹyin naa ẹ wo biriiji yii, eelo lo fẹẹ na yin lati ṣe atunṣe si i, kẹ ẹ digaga rẹ lati dena ki omi maa ya si oju titi? Ẹyin naa ẹ wo ero pitimu loju titi, wọn o jagun o, omi lo jẹ kawọn eeyan duro bẹẹ nitori o n gbe awọn eeyan lọ lataarọ ni”.

Nigba ti ọrọ naa ka a lara, obinrin yii kuku pariwo olori awọn aṣofin ipinlẹ Eko, Mudashiru Ọbasa, lati wo ipo tawọn eeyan ẹ wa, ati iru idaamu ti wọn maa n la kọja lasiko ojo. O ni nigba to ti jẹ pe awọn eeyan agbegbe ibẹ lo n ṣoju fun, ko yẹ ko jẹ inira fun un lati tun adugbo naa ṣe, ati gbogbo nnkan to ba le fa ijamba ẹmi ati dukia.

O ni, “Wo o, Ọbasa, adugbo ẹ ree, awọn eeyan n ku nibi, awọn to dibo fun ẹ n ku, ko le na ẹ ni nnkan kan lati ṣe e. Gbogbo yin lẹ n ko awọn ọmọ yin lọ siluu oyinbo, awọn ọmọ ọlọmọ ti ku.

Odidi kẹkẹ Maruwa to ko ero to kun, awọn eeyan ti wọn n wa nnkan ti wọn maa jẹ lọ, wọn jade lati wa nnkan ti wọn fẹẹ jẹ lọ ni o, ṣugbọn nnkan ti wọn fẹẹ jẹ ti jẹ wọn bayii o. Ọbasa, awọn to dibo fun yin ti n ku o, omi n gbe wọn lọ ni o. Omi ree, abatiọ (Abattoir) ree, iyalọja, omi n gbe awọn eeyan yin lọ o. Ṣe ẹ ti ri i, ko si wahala o’’.

Bayii ni obinrin naa sọ ninu fidio to gbe sori ẹrọ ayelujara.

Leave a Reply