Agbẹ to pa Fulani ni Kwara ni: O fi maaluu jẹko mi ni mo ṣe pa a  

Ibrahim Alagunmu, Ilorin

Ọkunrin agbẹ to yinbọn pa Fulani darandaran nipinlẹ Kwara, Sẹgun Adebayọ, ti sọ fun ile-ẹjọ Majistreeti kan niluu Ilọrin pe, Fulani ọmọ ọdun mejilelogun fi maaluu jẹko oun, loun ṣe yinbọn mọ ọn, to si gba ọrun lọ.

Majistreeti Ibrahim Dasuki ti waa paṣẹ ki wọn lọọ fi Adebayọ si ọgba ẹwọn to wa ni Oke-Kura, niluu Ilọrin, titi di ọjọ kejilelogun, oṣu kẹfa, ọdun ti a wa yii, ti igbẹjọ yoo waye.

Olupẹjọ, Zacchaeus Fọlọrunsọ, sọ fun ile-ẹjọ pe ẹgbọn oloogbe, Muhammad Adamu, lo mu ẹsun lọ si agọ ọlọpaa pe aburo oun da maaluu lọ, ko wale mọ.

Ṣugbọn nigba ti wọn mu Adebayọ lo jẹ wọ pe loootọ loun yinbọn pa Fulani yii, sugbọn oun ko jẹbi ẹsun ti wọn fi kan oun tori pe Fulani yii fi maaluu jẹ oko oun lo mu koun gbe igbesẹ naa. Adajọ ti ni ki Adebayọ lọọ maa gbatẹgun lọgba ẹwọn titi idajọ yoo fi waye.

Leave a Reply