Agbebọn kọ lu bọọsi elero mejidinlogun l’Akoko, wọn ji awọn eeyan inu rẹ gbe lọ

Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ

Awọn agbebọn kan tun ṣọṣẹ laarin Ikarẹ Akoko, nipinlẹ Ondo, si Ado-Ekiti, lalẹ ọjọ Abamẹta, Satide, ọjọ kẹẹẹdọgbọn, oṣu Karun-un, ọdun 2024 yii, pẹlu bi wọn ṣe da awọn arinrin-ajo kan lọna ninu ọkọ bọọsi elero mejidinlogun ti wọn wa, ti wọn si fipa ko wọn wọgbo lọ.

ALAROYE kọkọ fidi rẹ mulẹ lati ẹnu abilekọ kan, Mọriamọ Aliu, to n ṣiṣẹ agbẹ ninu igbo ọba to wa Imẹsi ati Egbe Ekiti, pe odidi bii ọgbọn iṣẹju lawọn ajinigbe ọhun fi ṣọṣẹ nitosi Irun Akoko ati Imẹsi Ekiti, ti ko si ṣẹni to di wọn lọwọ.

Abilekọ Mọriamọ ni asiko ti awọn n mura lati maa pada bọ wa siluu Ikarẹ Akoko, lati oko ti awọn ti lọọ ṣiṣẹ lọjọ iṣẹlẹ naa lawọn gbọ iroyin pe awọn ajinigbe ti gba oju ọna, ti wọn si n pa itu lọwọ.

O ni ohun ti awọn gbọ lẹyin-o-rẹyin ni pe ọkọ bọọsi elero mejidinlogun ni wọn da lọna, ti wọn si ti ko gbogbo ero inu rẹ lọ.

O ni awọn ṣọja ti wọn de sibi iṣẹlẹ naa lawọn eeyan fi raaye kọja lọ sibi ti wọn n lọ, ati pe awọn eeyan ti wọn ji gbe ọhun jẹ awọn ti wọn wa lati awọn ilu bii: Irun Akoko, Ikarẹ Akoko ati agbegbe Ekiti, nipinlẹ Ekiti.

Lẹyin wakati diẹ ti iṣẹlẹ ọhun waye ni wọn lawọn ẹsọ alaabo, ninu eyi ti awọn ṣọja, ọlọpaa, fijilante, awọn ọdẹ ati Amọtẹkun wa, ti ko ara wọn jọ, ti wọn si ti fọn sinu awọn aginju to wa lagbegbe naa lati lepa awọn ajinigbe ọhun.

Nigba to n fidi iṣẹlẹ yii mulẹ, Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ondo, Abilekọ Funmilayọ Ọdunlami, ni oun ko ti i le sọ ni pato iye awọn arinrin-ajo ti wọn ji gbe, ṣugbọn awọn ti bẹrẹ igbesẹ lori bawọn eeyan ọhun yoo ṣe maa di riri pada laipẹ.

O ni mẹrin ninu wọn ni wọn wa si teṣan lati waa fẹjọ sun pe, awọn agbebọn kan da awọn lọna, ti wọn si ji awọn gbe wọnu igbo lọ labule Oyinmọ, loju ọna Irun si Ado-Ekiti.

O ni awọn eeyan ọhun ṣalaye fawọn pe iṣẹlẹ ọhun waye lasiko ti awọn n pada si Ikarẹ Akoko lati Ado-Ekiti, ti awọn ti n bọ lọjọ yii.

Alukoro ni awọn mẹrẹẹrin ọhun ṣalaye pe niṣe lawọn fi ọgbọn sa mọ awọn ajinigbe naa lọwọ lẹyin ti wọn ko awọn wọnu igbo tan, ti awọn si pinnu lati wa si teṣan lati waa fi ọrọ ọhun to awọn ọlọpaa leti.

Ninu ọrọ tirẹ, Alakooso ẹṣọ Amọtẹkun fun ipinlẹ Ondo, Oloye Adetunji Adelẹyẹ ni, loootọ lawọn ẹṣọ alaabo lati ipinlẹ Ondo ati Ekiti ti fọn sinu igbo lati lepa awọn ọdaran naa, ki wọn si gba awọn awọn ẹni ẹlẹni ti wọn ji gbe silẹ lọwọ wọn.

Adelẹyẹ ni ki i ṣe gbogbo awọn ero mejidinlogun to wa ninu ọkọ naa ni wọn ji ko, nitori a ri awọn ti wọn raaye sa mọ awọn agbebọn ọhun lọwọ nibi ti wọn ti da wọn lọna, bẹẹ lawọn Amọtẹkun, pẹlu iranlọwọ awọn ṣọja naa tun ti ri awọn kan gba pada lalẹ ọjọ Abamẹta, Satide, ti iṣẹlẹ yii waye.

‘’Ohun ti awa gbọ lasiko ti a n ko iroyin yii jọ ni pe ọwọ awọn ẹṣọ alaabo ti pada tẹ ọkan ninu awọn agbebọn to ṣiṣẹ ibi naa.

‘’Aafin Onirun ti Irun Akoko, la gbọ pe wọn kọkọ mu afurasi ọhun lọ lati lọọ fọrọ wa a lẹnu wo ki wọn too fi i ṣọwọ si ọfiisi Eeria kọmanda awọn ọlọpaa to wa niluu Ikarẹ Akoko.

 

Leave a Reply