Agbebọn mẹfa ya bo ṣọọṣi lasiko ijọsin, wọn paayan kan, wọn ji ẹni mẹta gbe

Faith Adebọla

Ẹni ori yọ o di’le lọrọ da lọjọ Aiku, Sannde, ọsẹ yii, nigba tawọn janduku agbebọn ya bo ileejọsin ECWA (Evangelical Church of West Africa) kan to wa laduugbo Okedayọ, loju ọna Kabba si Okẹnẹ, nipinlẹ Kogi, ti wọn yinbọn pa ọkan lara awọn olujọsin naa, wọn si ko awọn mẹta tọwọ wọn ba wọgbo lọ.

Ọgbẹni Kayọde Akanbi, ọkan ninu awọn ọmọ ijọ tiṣẹlẹ yii ṣoju ẹ, sọ fun Ajọ Akoroyinjọ ilẹ wa (NAN) pe ni nnkan bii aago mẹwaa kọja iṣẹju mẹẹẹdogun owurọ lawọn afẹmiṣofo bii mẹfa naa de saduugbo ọhun, ti wọn si lọ taara si ṣọọṣi naa pẹlu aṣọ ṣọja ti wọn wọ, lasiko ti iwaasu n lọ lọwọ.

“Niṣe la kọkọ ro pe ọtọ ni ibi ti wọn n lọ ni, pe boya wọn kan fẹẹ gba iwaju ṣọọṣi kọja ni, afi bi wọn ṣe ya wọle, ti wọn si bẹrẹ si i yinbọn, lọrọ ba di bo-o-lọ-o-yago, bẹẹ iwaasu ti n lọ lọwọ nigba yẹn.

Awọn agbalagba ti wọn o le sare daadaa ni wọn gan lapa, ti wọn si ji wọn gbe lọ. Ko sẹni to le duro bi wọn ṣe n yinbọn kaakiri, nigba ti iro ibọn naa rọlẹ, tawọn ọlọpaa de, la ri i pe wọn ti yinbọn pa ọkan lara wa, ẹni ọdun marundinlaaadọta ni, ọta ibọn ṣe awọn mi-in leṣe, awọn kan si ṣeṣe bi wọn ṣe n sa asala fẹmii wọn lasiko akọlu naa.

A ti sare gbe awọn to fara pa lọ sọsibitu Jẹnẹra Kabba, nipinlẹ ọhun.”

Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Kogi, DSP William Aya, to fidi iṣẹlẹ yii mulẹ sọ pe awọn ti lọọ ṣabẹwo sibi iṣẹlẹ naa, awọn si ti bẹrẹ iwadii lati mọ ibi tawọn agbebọn naa ti wa ki wọn le doola ẹmi awọn ti wọn ji gbe.

Tẹ o ba gbagbe, ọsẹ to kọja yii lawọn agbebọn kan lọọ ya bo ọgba ẹwọn Kabba, nipinlẹ Kogi, leyii to mu kawọn ẹlẹwọn ojilerugba (240) sa lọ, bo tilẹ jẹ pe wọn ti ri ọgọrun-un kan o le mẹrinla mu ninu awọn ẹlẹwọn naa.

Leave a Reply