Agbegbe Guusu ko ni i dibo fun oludije to ba jade funpo Aarẹ latilẹ Hausa- Akeredolu

Faith Adebọla

Bo ba jẹ eeyan kan ṣakala lo sọrọ ọhun ni, boya iba da bii ọrọ apara, ṣugbọn Gomina ipinlẹ Ondo ni, Arakunrin Rotimi Akeredolu, to jẹ alaga gbogbo awọn gomina ipinlẹ Guusu ilẹ wa, o ni awọn ti pinnu lati ma ṣe tẹwọ gba ondije fun ipo aarẹ eyikeyii to ba jade lati apa Oke-Ọya ilẹ wa lọdun 2023, afi iha Guusu nikan.

“Ẹgbẹ oṣelu mẹta lawa gomina Guusu pin si, ẹgbẹ oṣelu All Progressive Congress (APC), ẹgbẹ oṣelu Peoples Democratic Party (PDP) ati All People Grand Alliance (APGA), ṣugbọn nipade wa, ko ṣeni to sọrọ to yatọ, ohun kan ṣoṣo ni gbogbo wa fi sọrọ, ipinnu kan ṣoṣo ta a fẹnu ko le lori ni pe aarẹ to kan lorileede yii gbọdọ wa lati iha Guusu nikan, a o si ni i kuro lori ẹ.”

Ọjọ Ẹti, Furaidee yii, l’Akeredolu tan imọlẹ sọrọ yii nigba to n dahun ibeere lori eto tẹlifiṣan Channels kan lori ipade tawọn gomina iha Guusu naa ṣe l’Ọjọbọ, Tọsidee, to ṣaaju.

Gomina naa ni “ọrọ tawọn kan n sọ pe ki i ṣe ibi ti Aarẹ ti wa lo ja ju, bi ko ṣe ki ẹni to fẹẹ dupo naa ni laakaye ati ọgbọn gidi, o lọrọ naa daa, ṣugbọn ko tẹwọn to, tori ko si agbegbe tabi iha kan lorileede yii ti ko ni awọn eeyan onilaakaye ati ọlọgbọn, bi wọn ṣe wa nilẹ Guusu naa lo wa nilẹ Hausa, eyi lo fi jẹ pe agbegbe ti wọn ti jade lawọn maa fun lafiyesi ju.

Ẹgbẹ oṣelu to ba lọọ fa ondije kalẹ lati agbegbe Oke-Ọya gbọdọ mura lati koju awọn eeyan Guusu ati ijọba ipinlẹ wa gbogbo tori mo mọ pe wọn o ni i tẹwọ gba a, ko sẹni to maa sọpọọti ẹ.

Ipinnu wa ki i ṣe ti oṣelu, iyẹn si lẹnu wa fi ko lori eyi. Dandan ni ki a ṣe e ni “jẹ ki n jẹ ni,” ti Aarẹ Buhari ba fi wa lori aleefa fun ọdun mẹjọ gbako, ko tun le jẹ agbegbe yẹn ni aarẹ to kan ti maa wa mọ, idajọ ododo ati ẹtọ ti a n waasu ẹ niyẹn,” Akeredolu lo ṣalaye bẹẹ.

Leave a Reply