Faith Adebọla
Arọwa ti lọ sọdọ Ọọniriṣa, Ọba Ẹnitan Ogunwusi, Ọjaja Keji, lati da si ọrọ awọn ọmọọṣẹ Sunday Igboho meji to ṣi wa lahaamọ ileeṣẹ ọtẹlẹmuyẹ apapọ DSS l’Abuja kawọn afurasi naa le dẹni ominira bii tawọn ẹgbẹ wọn.
Amofin Pẹlumi Ọlajẹngbesi, lọọya to ṣaaju awọn agbẹjọro ti wọn n ṣoju awọn mejila ti wọn mu nile Sunday Igboho lọjọsi, lo kọ lẹta pataki kan si Ọba Adeyẹye Ẹnitan Ogunwusi lọjọ Aje, Mọnde, ọsẹ yii, pe ki ọba naa lo ipo rẹ lati ba Aarẹ ilẹ wa, Muhammadu Buhari, ati awọn alaṣẹ ijọba apapọ sọrọ ki wọn le tu awọn meji ọhun silẹ.
Orukọ awọn meji naa tawọn oṣiṣẹ DSS kọ lati yọnda ni Amudalat Abibat Babatunde ati Jamiu Noah Oyetunji.
Ọlajẹngbesi ṣalaye pe loootọ nile-ẹjọ ti yọnda beeli fawọn eeyan naa, tawọn si ti ṣe gbogbo eto to yẹ lati kaju beeli, leyii to mu ki wọn fi awọn mẹwaa lara wọn silẹ, ṣugbọn ti wọn taku lori awọn meji to ṣẹku ọhun.
Amofin naa gboṣuba fun Ọọniriṣa, o lawọn mọ pe ẹni-ọwọ lọba alaye naa lọdọ ijọba, olugbeja gbogbo ọmọ Yoruba ni, awọn si fẹ ko lo anfaani yii lati da sọrọ naa, ko ba Aarẹ Muhammadu Buhari sọrọ, ki wọn le tu awọn ọmọ Sunday Igboho mejeeji to ku yii silẹ laipẹ, paapaa nitori ipo ailera ti Amdalat wa.
Ọlajẹngbesi ni iwa tawọn DSS hu yii ko dara, pẹlu bi wọn ṣe kọ lati tẹle aṣẹ ile-ẹjọ delẹdelẹ.