Agbẹjọro lọ si kootu pẹlu aṣọ ẹsin abalaye, o ni idajọ ile-ẹjọ to ga ju lọ loun tẹle

Jọkẹ Amọri

Pẹlu iyanu lawọn eeyan fi n wo ọkunrin agbẹjọro ajafẹtọọ ọmọniyan kan, Malcom Omoirhobo, to lọ sile-ẹjọ giga to ga ju lọ niluu Abuja pẹlu aṣọ ẹsin abalaye l’Ọjọbọ, Tọsidee, ọsẹ yii.
Ọkunrin to wọ ṣokoto pupa lori ẹwu funfun, to waa wọ aṣọ awọn agbẹjọro le e lori so ado mọ ọrun rẹ, bẹẹ lo so ilẹkẹ mọ ẹsẹ rẹ, to si so iyẹ mọ fila agbẹjọro to de, o waa fi ẹfun funfun yi oju rẹ osi po. Bẹẹ ni ko wọ bata wọnu kootu naa, ẹsẹ rẹ lo fi rin. O ni Oriṣa Olokun loun n bọ, bi awọn si ti maa n mura nibẹ loun ṣe mura yii.
O ni oun gbe igbesẹ lati mura nilana awọn ẹlẹsin Olokun yii lati ṣafihan ẹtọ ti oun ni labẹ ofin ilẹ Naijiria pẹlu idajọ ile-ẹjọ to ga ju lọ nilẹ wa to fun awọn akẹkọọ Musulumi nipinlẹ Eko lanfaani lati maa lo ijaabu lọ sileewe ati lawọn ibi kaakiri.
O ran awọn eeyan leti pe ni ọjọ Ẹti, Furaidee, ni ile-ẹjọ to ga ju lọ nilẹ wa fọwọ si i pe ki awọn akẹkọọ-binrin ileewe girama nipinlẹ Eko maa lo ijaabu. Marun-un ninu awọn adajọ naa ni wọn fọwọ si i pe ki awọn akẹkọọ-binrin yii maa lo ijaabu, nigba ti marun-un ko fọwọ si i.
Ni nnkan bii aago mẹsan-an kọja iṣẹju marun-un ni ọkunrin naa wọ yara igbẹjọ wa. Pẹlu iyalẹnu lawọn agbẹjọro ẹgbẹ rẹ fi n wo o nigba to wọ yara igbẹjọ naa pẹlu aṣọ awọn ẹlẹsin abalaye. Niṣe lo si sọ fun awọn agbofinro to lọọ ba a pe wọn ko lẹtọọ lati le oun jade nile-ẹjọ naa nitori oun ni ẹtọ labẹ ofin lai si ẹnikẹni ti yoo halẹ mọ oun.
Nigba to n ba awọn oniroyin sọrọ, Malcom ni, ‘‘Mo dupẹ lọwọ ile-ẹjọ to ga ju lọ nilẹ wa fun idajọ fun ipinnu ti wọn ṣe lati faaye gba apa kejidinlogoji ofin ilẹ wa. Eyi to sọ pe a ni anfaani si ero, iṣe ati ijọsin to ba wu wa. Eyi to tumọ si pe a lẹtọọ lati ṣe amulo imura ẹsin to ba wu wa ni awọn ileewe tabi ni ita gbangba. Ipinnu ile-ẹjọ naa lo jẹ iwuri fun mi ti mo fi mura bayii wa.
‘‘Nitori pe mo jẹ ẹlẹsin abalaye, ọna ti mo si n gba ṣe ẹsin mi ree. Pẹlu aṣẹ ile-ẹjọ yii, bi mo ṣe maa maa mura wa si kootu ree nigbakugba ti mo fẹẹ wa nitori Oriṣa Olokun ni mo n sin.’’
Bẹẹ ni ọkunrin naa sọ.

Leave a Reply