Ibrahim Alagunmu, Ilọrin
Ile-ẹjọ Magistreeti kan niluu Ilọrin, ti sọ agbẹjọro kan, Abdulfai Yusuf, sọgba ẹwọn Oke-Kura, niluu Ilọrin, fẹsun pe o lu onibaara rẹ, Ọmọniyi Asiwaju, ni jibiti miliọnu meji Naira.
Aṣiwaju lo mu ẹsun lọ siwaju ile-ẹjọ pe agbẹjọro oun, Yusuf, ba oun ta dukia kan towo rẹ to miliọnu meji Naira, ti ko si ko owo naa kalẹ, gbogbo ipa ni oun sa lati ri owo naa gba, ṣugbọn pabo lo ja si.
Agbefọba, Innocent Owoọla, sọ fun ile-ẹjọ pe latigba ti ile-ẹjọ ti fiwe pe Yusuf ni ko ti dahun, to n sa kiri. Eyi lo mu ki Onidaajọ A. O. Shuaib paṣẹ pe ki wọn sọ Yusuf si ahamọ ọgba ẹwọn Oke-Kura, titi ti agbẹjọro rẹ yoo fi gbe igbesẹ to yẹ. Lẹyin eyi lo sun igbẹjọ si ọjọ kẹtadinlogun, oṣu Kẹwaa, ọdun yii.