Agbekọya atawọn ọmọ Auxilliary gbena woju ara wọn n’Ibadan

Ọlawale Ajao, Ibadan

Ibẹrubojo gba ọkan awọn araadugbo Idi-Apẹ, n’Ibadan, nigba tawọn ọmọ Alhaji Mukaila Auxilliary, ọga awọn onimọto n’Ibadan, fija pẹẹta pẹlu awọn Agbẹkọya, iyẹn awọn ajijagbara ti wọn tun fẹẹ da bii awọn ọmoogun ilẹ Yoruba.

Ni nnkan bii aago mẹta Ọjọruu, Wẹsidee, ọsẹ yii, niṣẹlẹ yii waye laduugbo Idi-Apẹ.

Wahala ọhun bẹrẹ nigba ti Auxilliary to jẹ oludari awọn agbowo-ita lọwọ awọn onimọto nipinlẹ Ọyọ n kọja lọ laduugbo naa, tawọn ọmọ ẹyin ẹ si bẹrẹ si i dalẹ ru, ti wọn n da awọn awakọ gbogbo duro ki ọga wọn fi le kọja.

Ṣugbọn awọn ajijagbara ti wọn n pe ni Agbẹkọya yii ko ri idi ti gbogbo eeyan ṣe gbọdọ duro bẹẹ nitori ẹnikan ti ki i ṣe oga agbofinro tabi ẹnikan to wa nipo olori ijọba. O jọ pe eyi lo fa a ti wọn ṣe kọ lati duro fun olori awọn onimọto naa, wọn ta ko aṣẹ awọn ọmọ Mukaila baba Akiimu.

Iwa ibajẹ ati afojudi nla lawọn ọmọ yuniọọnu ka eyi si, nitori naa, lọgan ni wọn ya lu awọn ẹgbẹ ajijagbara naa, ti wọn si bẹrẹ si i lu wọn bii ole tọwọ tẹ laarin ọja.

Gẹgẹ bawọn ti ṣẹlẹ ọhun ṣoju wọn ṣe royin, Auxilliary funra ẹ to sọ kalẹ ninu mọto rẹ lọọ la wọn nija ni ko jẹ ki ọrọ naa di ija nla to ṣee ṣe ki wọn tori ẹ para wọn silẹ.

Adura ti pupọ ninu awọn ara agbegbe Idi-Apẹ si Iwo Road n gba titi ta a fi pari akojọ iroyin yii ni pe ki ọrọ naa ma di ohun ti awọn Agbẹkọya yoo tun tori ẹ mura ija waa ka awọn onimọto agbegbe naa mọle, ko ma lọọ di ija igboro to le tun di ohun ti wọn yoo maa fẹmi awọn eeyan ati dukia ṣofo.

Leave a Reply