Agbọọla Ajayi balẹ gudẹ sinu ẹgbẹ ZLP, o loun lawọn eeyan ipinlẹ Ondo n fẹ

Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ

Ọjọ Ẹti, Furaidee, ọsẹ yii, ni Igbakeji Gomina ipinlẹ Ondo, Ọnarebu Agboọla Ajayi, fi ipinnu rẹ han fawọn eeyan ipinlẹ naa pe oun ti darapọ mọ ẹgbẹ oṣelu ZLP.

Ikede ita gbangba yii lo waye ni olu ile ẹgbẹ naa to wa lagbegbe Lafẹ, niluu Akurẹ.

Ọgọọrọ awọn ọmọ ẹgbẹ yii ni wọn tu yaaya jade lati fi ayọ wọn han ati lati ki ọkunrin ọmọ bibi ilu Kiribo, nijọba ibilẹ Ẹsẹ-Odo, ọhun kaabọ.

Alaga ẹgbẹ ZLP nipinlẹ Ondo, Joseph Akinlaja ni awọn iṣẹ nla ti ijọba Mimiko ṣe laarin ọdun mẹjọ to fi wa lori aleefa ko ṣee fọwọ rọ sẹyin.

O ni inu awọn dun pupọ pe Ajayi fẹẹ dije lorukọ ẹgbẹ ZLP, ki awọn iṣẹ idagbasoke tijọba to wa lode ti pa ti le tẹsiwaju.

Ajayi funra rẹ fi awọn eeyan lọkan balẹ pe ko ni i sọrọ ojooro ninu eto idibo to n bọ. O ni ọnakọna tawọn ẹgbẹ APC le fẹẹ gba lati ṣeru lawọn ti n mura silẹ de.

Lẹyin ayẹyẹ ti wọn ṣe l’Akurẹ ni wọn tun mori le ilu Ondo, nibi ti wọn ti lọọ fa igbakeji gomina ọhun le Dokita Olusẹgun Mimiko lọwọ.

Leave a Reply