Agboọla ati Tunde fọ ṣọọbu n’Igede-Ekiti, ounjẹ ti wọn ji nibẹ ko din ni miliọnu kan

 Taofeek SurdiqAdo-Ekiti

Nigba ti awọn ọkunrin meji kan, Ogunkuade Agboọla; ẹni ogoji ọdun, ati ọrẹ rẹ, Ajayi Tunde; ẹni ọdun mọkanlelogoji, fọ ṣọọbu kan ti wọn ti n ta ounjẹ tutu lapo-lapo n’Igede-Ekiti loṣu kẹsan-an to kọja yii, ikanra ni wọn fi bẹrẹ si i gbe apo irẹsi, apo ẹwa, ororo, Indomie atawọn nnkan mi-in tẹnu n jẹ. Nigba ti wọn yoo si fi ṣọṣẹ naa tan, apapọ ohun ti wọn ji ni ṣọọbu ọhun ko din ni miliọnu kan naira.

Ohun ti Alukoro ọlọpaa ipinlẹ Ekiti, Sunday Abutu, sọ lori iṣẹlẹ naa lẹyin tọwọ tẹ awọn ọkunrin meji yii ni pe ọjọ kẹfa, oṣu kẹsan-an, ọdun 2021 yii, ni awọn ọrẹ meji ọhun wọ ṣọọbu obinrin kan torukọ ẹ n jẹ Stella Ọpẹyẹmi.

O ni Oke-Aga, n’Igede-Ekiti, ni ṣọọbu obinrin naa wa, nibi to ti n ta awọn nnkan tẹnu n jẹ lapo-lapo, to si tun n ta awọn atẹ wẹwẹ mọ ọn.

Lẹyin ti awọn afurasi naa fọ ṣọọbu ọhun tan, ọwọ ọlọpaa ko tete tẹ wọn, wọn ti ta ninu ẹ daadaa ko too di pe ọwọ ofin mu wọn lasiko yii.

Eyi ni ọja yooku tawọn ọlọpaa ri gba lọwọ wọn gẹgẹ bi Alukoro ọlọpaa Ekiti ṣe ṣalaye: Apo irẹsi mẹfa, ilaji apo ẹwa kan, galọọnu ororo marun-un, paali tumaati nla nla mẹrin, paali miliiki mẹrin, paali Indomie mẹrin ati apo fulawa Golden Penny marun-un.

Apapọ owo awọn ohun jijẹ wọnyi ko din ni miliọnu kan naira gẹgẹ bi Abutu ṣe wi.

Lori bi wọn ṣe ri Agboọla ati Tunde mu, ọlọpaa yii sọ pe awọn eeyan kan ni wọn ta awọn lolobo nipa wọn, awọn si bẹrẹ iwadii to le gan-an, lẹyin iwadii naa lọwọ tẹ wọn.

O ni ko ni i pẹ rara ti awọn yoo fi ko awọn mejeeji lọ sile-ẹjọ lati ṣalaye ara wọn.

 

Leave a Reply