Agolo tomato l’Okorie fẹẹ fi gbe egoogi oloro lọ siluu oyinbo tọwọ fi tẹ ẹ l’Ekoo

Faith Adebọla, Eko

Wọn ti ni ki gbogbo ẹni to ba mọ nnkan i fi pamọ maa ranti ẹni to mọ nnkan i wa lawakan, eyi lo difa fun ọkunrin oniṣowo egboogi oloro to filu Eko ṣe ibugbe yii, Eze Celestine Okorie, tomato alagolo nla lo loun fẹẹ ko lọ fawọn eeyan oun kan niluu eebo, aṣe irọ lo n pọn lewe, egboogi oloro ni jagunlabi rọ sinu ẹ, lọwọ ba to o.

Agbẹnusọ fun Ajọ to n fimu awọn to n gbe egboogi oloro danrin, National Drug Law Enforcement Agency (NDLEA), Ọgbẹni Fẹmi Babafẹmi, lo jẹ k’ALAROYE gbọ nipa iṣẹlẹ yii ninu atẹjade kan to fi lede lọjọ Aiku, Sannde yii, o ni papakọ ofurufu Muritala Mohammed, eyi to wa n’Ikẹja, l’Ekoo lọwọ awọn agbofinro ti tẹ afurasi ọdaran yii, laarin ọsẹ to kọja.

Ilu London, lorileede United Kingdom, lo ni Okorie sọ p’oun n ko tomato alagolo lọ, o loun fẹẹ fi ṣọwọ si wọn lọhun-un ni, dẹrẹba ileeṣẹ to n ba ni gbe ẹru lo sanwo fun, awọn ni wọn gbe baagi naa wa.

Ṣugbọn baagi naa ko le kọja nigba ti wọn gbe e sori ẹrọ atanilolobo ti wọn fi n yẹ ẹru wo, lawọn agbofinro ba mu dirẹba naa, wọn ni ko jẹwọ ibi to ti ri ẹrukẹru to n gbe kiri, ko si ṣalaye ohun to wa ninu ẹru, ni dẹrẹba ba ni wọn fi ẹru ran oun ni, kidaa aṣọ imurode ati tomato alagolo toun fẹẹ fi i ta awọn eeyan oun niluu eebo lọrẹ lo loun ko sinu baagi ọhun, gbogbo agolo tomato naa si ni wọn ti jo pa loootọ, ko sẹni to le fura pe tomato irọ lo wa ninu wọn.

Ṣa, wọn gbe ẹru de ibudo NAHCO lati tubọ wo iru tomato ọran yii, bi wọn ṣe ja agolo kan laṣiiri ba tu, lailọọnu dudu ni wọn fi we egboogi oloro ti wọn n pe ni methamphetamine lede eleebo, ọmọọya kokeeni legboogi ọhun, iwọn kilo mẹrin aabọ lo wọn nigba ti wọn ṣodiwọn gbogbo ẹ.

Ni wọn ba tẹle dẹrẹba yii lọjọ keji, pe ko mu wọn lọọ sọdọ ẹlẹru, ibẹ lọwọ ti ba Okorie lagbegbe Coker, ni Surulere to n gbe, ni wọn ba fi dẹrẹba silẹ, wọn wọn ẹlẹru ofin sọkọ, atoun ati ẹru ẹsibiiti rẹ ni wọn gbe lọ sọdọ awọn ọlọpaa ọtẹlẹmuyẹ, ki wọn le tubọ ṣewadii si i.

Wọn lọkunrin naa jẹwọ pe ọmọ bibi abule Isu, nijọba ibilẹ Onicha, ipinlẹ Ebonyi loun, ṣugbọn okoowo egboogi oloro loun n ṣe l’Ekoo, awọn si pọ tawọn jọ n ṣe e.

Ọbafẹmi ni iwadii ṣi n tẹsiwaju lori ọrọ ọhun.

Leave a Reply