Mejidinlogoje ninu awọn agunbanirọ to fẹẹ sinjọba ti ko arun koronafairọọsi

Jide Alabi

Awọn agunbanirọ ti wọn jẹ mejidinlogoje (138) ni ajọ to n gbogun ti ajakalẹ arun ti sọ pe wọn ti lugbadi arun koronafiarọọsi bayii.

Lọjọ Aje, Mọnde, ọsẹ yii, ni Ọga agba, Chikwa Ikekweazu fun ajọ to n gbogun ti ajakalẹ arun ni Naijiria sọrọ yii niluu Abuja.

O ni aṣeyọri nla ni ajọ naa ti ṣe bayii pẹlu bi eto isinlu ẹni ti ṣe bẹrẹ pada, ati pe ninu awọn agunbanirọ ti wọn ṣẹṣẹ wọ ibi ipagọ fun igbaradi lati sin orilẹ-ede yii lawọn ti ri mejidinlogoje ninu wọn ti wọn ti lugbadi arun ọhun bayii.

O fi kun un pe awọn agunbanirọ ti wọn yoo sinlu lọdun yii fẹẹ to ẹgbẹrun marundinlogoji (34,785), ati pe ninu wọn naa lawọn ti ri awọn ti wọn ko arun korona, ti wọn si ti n gba itọju bayii.

Lara eto ti ajọ to n mojuto eto isinlu, NYSC, ṣe ni pe wọn ko jẹ ki awọn ti wọn ni arun yii darapọ mọ awọn to ti wa nibi ipagọ ti wọn ko ni in lara.

Leave a Reply