Agunbanirọ pade iku ojiji lasiko to n pada lọ sibi to ti n sinjọba ni Kwara

Ibrahim Alagunmu, Ilọrin
Ki Ọlọrun ma jẹ ki abiamọ foju sunkun ọmọ ni o, Ọlalẹyẹ Bukọla Olukolade (IM/22A/2156), to jẹ agunbanirọ ti wọn gbe lọ si ipinlẹ Imo lati lọọ sin ilẹ baba rẹ fun ọdun kan gbako ti kagbako iku ojiji nibi ijamba ọkọ lasiko to n pada si ipinlẹ Kwara lẹyin oṣu mẹta to lo ni ipagọ idanilẹkọọ agunbanirọ nipinlẹ Imo.
Iṣẹlẹ ijamba ọkọ naa ni ALAROYE gbọ pe o waye nigba to ku diẹ ki ọkọ ọhun wọ ilu Ilọrin, nigba ti awakọ naa sọ ijanu ọkọ nu, ti ko si ri i dari mọ.
Adari ajọ agunbanirọ nipinlẹ Ọyọ, Arabinrin Grace Ogbuogebe, ti ṣe abẹwo si mọlẹbi Bukọla to doloogbe lọjọ Aje, Mọnde, ọṣẹ yii, ni agboole awọn mọlẹbi rẹ to wa ni Ilọra, nijọba ibilẹ Afijio, nipinlẹ naa.
Ogbuogebe to ṣoju adari agba ajọ agunbanirọ nilẹ yii, Ọgagun Shuaibu Ibrahim, juwe iku ọmọ ọhun gẹgẹ bii eyi ti ki i ṣe adanu nla fun mọlẹbi oloogbe nikan, ṣugbọn fun orile-ede Naijiria lapapọ.
Lẹyin naa lo fun awọn mọlẹbi ọmọbinrin naa lowo ‘gba ma binu’ lorukọ alaṣẹ agunbanirọ.

Leave a Reply