Agunbanirọ yii yoo ṣẹwọn o, oyinbo lo lu ni jibiti owo nla ni Kwara

Stephen Ajagbe, Ilorin

Agunbanirọ kan, Sam Abiọla, lajọ to n gbogun tiwa jibiti, EFCC, nipinlẹ Kwara, wọ lọ sile-ẹjọ giga ilu Ilọrin, lọjọ Aje, Mọnde, ọsẹ yii, fẹsun ṣiṣe jibiti ori ẹrọ ayelujara.
Abiọla, to n sirinlu nipinlẹ Kogi, laarin oṣu keje si ikẹsan-an, ọdun 2019, lo ayederu orukọ oyinbo obinrin, Missie Bonie, ati nọmba foonu kan; +19287060683, lati fi tan ọkunrin oyinbo kan torukọ rẹ n jẹ, Rick, pe oun nifẹẹ rẹ, to si gba ọgọrun-un marun-un dọla lọwọ onitọhun.
Nigba tile-ẹjọ ka ẹsun rẹ si i leti, olujẹjọ naa loun jẹbi.
Bakan naa, afurasi kan, Adebiyi Sọdiq, foju bale-ẹjọ fẹsun kan naa.
Adebiyi to n pe ara rẹ ni ‘Maria Monica’ oyinbo alawọ funfun, ninu oṣu kẹjọ, ọdun 2020, lo ikanni gmail kan; terrellwhite856@gmail.com, lati maa fi gba owo lọwọ ẹnikan to n jẹ Manny.
Olujẹjọ ọhun naa gba pe loootọ loun jẹbi ẹsun naa.
Agbẹjọro ijọba, Ọgbẹni O.B Akinṣọla, pe ẹlẹrii kan, Ali Mohammed, oṣiṣẹ ajọ EFCC siwaju ile-ẹjọ lati ṣalaye bi ẹjọ naa ṣe lọ.
Mohammed ṣalaye pe agbegbe ilu Ọffa lawọn ti mu awọn afurasi naa. O ni ẹnikan to forukọ bo ara rẹ laṣiri lo kọwe sileeṣẹ awọn, to si ta awọn lolobo nipa ohun ti wọn n ṣe.
Ni ti Sọdiq, Agbefọba, Sẹsan Ọla, pe oṣiṣẹ EFCC, Eze Uchenna, lati ṣalaye bi ẹjọ naa ṣe jẹ. Iyẹn ko awọn ẹri to daju silẹ, eyi to fi han pe loootọ afurasi naa lọwọ ninu jibiti ori intanẹẹti.
Adajọ Adenikẹ Akinpẹlu sun idajọ si ọjọ kọkanla, oṣu keji, ọdun yii.

Leave a Reply