Gbenga Amos, Ogun
Iyaale ile kan, Mariam Ayinla, afurasi ajinigbe ẹni ọdun mẹtadinlọgbọn kan ti lọọ ji ọmọọdun mẹtala kan, Sọfiat Yuṣau, gbe l’Atan-Ọta, nipinlẹ Ogun, ọrọ naa si ti bu u lọwọ gidigidi bayii o, afaimọ ni ki i ṣe inu ahamọ awọn ọlọpaa tabi ọgba ẹwọn ni yoo ti ṣe Keresi tiẹ.
Irọlẹ ọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ogunjọ, oṣu Kẹjila yii, lọwọ awọn agbofinro lati ẹka ileeṣẹ wọn to wa niluu Agbara, nipinlẹ Ogun, dọdẹ obinrin naa, ti wọn si fi pampẹ ofin gbe e.
Alaroye gbọ pe Baba Sọfiat, iyẹn Ọgbẹni Ismail Yuṣau, lo kegbajare lọ si teṣan ọlọpaa lọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọhun, to ni ki wọn gba oun, oun ti reemọ, ọmọ oun toun ran niṣẹ pe ko ba oun ra nnkan wa laduugbo awọn lati aago mọkanla aarọ, ọmọ naa ti dawati, bẹẹ ibi toun ran an ko ju ile kẹfa sibi toun n gbe lọ.
O ni riri toun maa ri i lẹyin naa ni bi ipe ajoji ṣe wọle sori foonu oun, nibi toun ti n ṣe sagba-sula kiri lati mọ ibi tọmọ naa ha si lẹnikan toun o mọ ri ti ba oun sọrọ pe ọmọ oun wa lakata awọn ajinigbe, awọn ti ji i gbe, koun ma wulẹ daamu mọ, owo ni koun lọọ wa, ẹgbẹrun lọna aadọtalerugba (N250,000) ni koun ko wa ni kiakia toun ba ṣi nilo ẹmi ọmọ oun, aijẹ bẹẹ, oun ko ni i foju kan ọmọ ọhun mọ, oku ẹ lawọn maa fi ṣọwọ soun.
DPO teṣan Agbara, CSP Abiọdun Salau, lo sare ṣeto awọn ọtẹlẹmuyẹ, awọn ọmọran ti i moyun igbin ninu ikarawun, ti wọn ti da lẹkọọ lori wiwa nọmba foonu ti wọn ba fi pamọ ati beeyan ṣe n fi ẹrọ igbalode wadii ijinlẹ, awọn ni wọn fori kori lori iṣẹlẹ ọhun, wọn wa nọmba foonu ti wọn fi pe baba ọmọ yii kan, wọn si tọpa afurasi ọdaran ọhun de ibuba to gbe ọmọọlọmọ pamọ si lagbegbe Atan-Ọta, ni wọn ba mu un, wọn si gba Sọfiat kuro lakata rẹ.
Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ogun, SP Abimbọla Oyeyẹmi, sọ f’ALAROYE pe iwadii ti wọn ṣe fihan pe ọmọ tuntun ki i ṣe akọpa ajẹ fobinrin yii, wọn lo gbowọ nidii iṣẹ gbọmọgbọmọ, tori lọjọ to ṣaaju ọjọ ti wọn mu un yii, iyẹn ni Mọnde, ọjọ kọkandinlogun, oṣu Disẹmba yii, kan naa, o ti kọkọ ji ọmọbinrin kan gbe lagbegbe Itele Ọta, bakan naa lo si ṣe pe obi awọn ọmọbinrin naa, to gbowo nla lọwọ wọn, ko too tu ọmọbinrin naa silẹ. Amọ ijẹ ana dun mọ ehoro rẹ lẹnu to fi tun lọọ ji Sọfiat gbe, laimọ pe ọwọ palaba oun o ni i pẹẹ segi.
Ṣa, Kọmiṣanna ọlọpaa ipinlẹ Ogun, CP Lanre Bankọle, ti paṣẹ pe ki wọn taari afurasi naa sẹka awọn ọtẹlẹmuyẹ to n tọpinpin iwa ijinigbe lolu ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ogun, o ni ki wọn tubọ tuṣu deṣalẹ ikoko, lati mọ awọn to n kun afurasi yii lọwọ ati bo ṣe n ṣiṣẹẹbi rẹ.
O ni igba tiwadii ba pari, awọn maa wọ ọ dele-ẹjọ, ki wọn le kawe ofin si i leti, ko si gba idajọ to ba tọ si i.