Aisan kọlẹra pa eeyan mọkanla nijọba ibilẹ Lagelu, n’Ibadan

Jide Alabi

Eeyan mọkanla ni wọn ti pade iku ojiji bayii, ti wọn si sare gbe eeyan marun-un mi-in lọ sọsibitu, nigba ti aisan kan ti wọn gbagbọ pe onigba-meji tabi kọlẹra ṣadeede bẹ silẹ nijọba ibilẹ Lagelu, niluu Ibadan, ipinlẹ Ọyọ.

Ohun ti awọn eeyan agbegbe naa n sọ ni pe o ṣee ṣe ko je pe aisan kọlera lo kọ lu wọn, nitori niṣe ni awọn to kọ lu n ṣu, ti wọn si tun n bi gidigidi.

Ṣa o, ijọba ti sọ pe oun ko ti i le sọ pe ohun to ṣe wọn gan-an niyẹn, niwọn igba ti esi ayẹwo ti wọn ṣe ko ti i de lati ibi ti wọn ti lọọ yẹ ẹ wo.

Abule kan ti wọn n pe ni Ariku niṣẹlẹ ọhun ti kọkọ waye, nibi ti eeyan marun-un ti ba iṣẹlẹ ọhun lọ.

Lẹyin ẹ ni iroyin tun gba ilu pe ohun to n ṣe wọn ni Ariku naa tun ti tan de Lagun, ko si pẹ ti awọn eeyan mẹfa fi ku nibẹ naa.

Alamoojuto ijọba ibilẹ Lagelu ti sọ pe loootọ niṣẹlẹ ọhun waye, ati pe eeyan mọkanla lo ti ba a rin bayii.

Ninu eeyan marun-un ti wọn gbe digbadigba lọ si ọsibitu, wọn ni mẹrin ti wa sile ninu wọn, nigba ti wọn ṣi n tọju ẹni kan lọwọ.

Leave a Reply