Aisha Buhari beere fun ajẹmọnu ati owo ifẹyinti fawọn iyawo aarẹ

Monisọla Saka
Iyawo Aarẹ orilẹ-ede wa to n palẹmọ ati kogba sile, Aisha Buhari, ti gbẹnu awọn iyawo aarẹ to ti jẹ tẹlẹri, atawọn to n bọ lẹyin sọrọ. O ni o yẹ kijọba ṣeto awọn anfaani ati ajẹmọnu kan, iru eyi tawọn Aarẹ n jẹ fawọn naa.
O lawọn nnkan bii ọkọ ayọkẹlẹ, eto ilera-ọfẹ, owo ajẹmọnu atawọn nnkan mi-in to le ṣanfaani fawọn naa gẹgẹ bii awọn ọkọ awọn.
Obinrin yii ni o ṣe pataki lati jẹ kawọn naa jẹ anfaani bii tawọn ọkọ awọn, nitori nigba ti wahala kan ba de, ko sẹni to fẹẹ mọ boya eeyan o si nipo agbara mọ.
O ni, “Mo n tẹnumọ ọrọ naa nitori pe mo fẹ ọkọ mi gẹgẹ bii iyawo aarẹ tẹlẹri. Ni ọjọ perete si isinyii ni a n lọ, mo si tun n lọ bii iyawo aarẹ atijọ fun igba keji. O yẹ ki wọn wo awa naa ṣe gẹgẹ bii iyawo aarẹ atijọ. Ki wọn fi tiwa naa kun un, ki wọn fun wa lawọn anfaani ati oore-ọfẹ kan to tọ si wa gẹgẹ bii iyawo aare, ko ma jẹ ti tawọn Aarẹ nikan ni wọn yoo máa mojuto”.
Nibi eto ifilọlẹ iwe ti aarẹ ẹgbẹ awọn iyawo ọlọpaa atawọn ologun nilẹ wa, Defence and Police Officer’s Wives Association (DEPOWA), Arabinrin Vickie Anwuli Irabor, ṣe niluu Abuja, eyi to pe akọle rẹ ni “Irinajo iyawo Ologun” (The Journey of a Millitari Wife), ni Aisha ti sọrọ yii lọjọ Ẹti, Furaidee, ọjọ kẹrindinlọgbọn, oṣu Karun-un, ọdun yii.
Nigba ti Aisha n gboṣuba kare fun obinrin to kọwe naa, o ni, “Okodoro ọrọ, iwe to n mu ori ẹni wu, ti yoo si ran awọn iyawo ologun lọwọ lati rin irinajo aye wọn ni. Bakan naa niwe ọhun tun ṣafihan awọn obinrin gẹgẹ bii nnkan to mu orilẹ-ede duro, agaga lasiko ti ọrọ awọn agbesunmọmi ati eto aabo dide ogun si ilẹ yii”.
O fi kun un pe iwe itọsọna fawọn iyawo ọmọ ogun ilẹ Naijiria ni, yoo si tun jẹ kawọn eeyan dide iranwọ fawọn opo tawọn ologun to ti ku fi silẹ lọ, ati pe gbogbo awọn nnkan ti onkọwe tọka si yoo jẹ kawọn eeyan, paapaa ju lọ awọn ti wọn ba kawe naa, le mọ adojukọ tawọn mọlẹbi ologun n ni.

Leave a Reply