Aisha Buhari fiwe pe awọn oludije dupo aarẹ, o ni ki wọn ma mu foonu wọn dani wa

Mosunmọla Saka
Gbogbo awọn oludije dupo aarẹ kaakiri awọn ẹgbẹ oṣelu nilẹ Naijiria ni wọn yoo peju pesẹ si gbọngan ile ijọba ilẹ wa laago mẹfa aabọ ọjọ Abamẹta, Satide, ọjọ kẹtalelogun, oṣu Kẹrin, ọdun 2023, lati ṣinu pẹlu obinrin akọkọ nilẹ wa, Aisha Muhammadu Buhari.

Ninu iwe ipe ọhun ni wọn ti ni ki awọn ti wọn fiwe pe ma mu foonu wa, yatọ si kaadi ipeni wọn, eyi ti wọn yoo fi wọle.
Amọ ṣa, ọrọ yii ko kan Igbakeji Aarẹ, Yẹmi Ọṣinbajo, awọn gomina atawọn minisita ti wọn n reti nibi ipade ọhun.
Nigba to n fidi ọrọ ọhun mulẹ, agbẹnusọ iyawo Aarẹ, Aliyu Abdullahi, ni “Ko si nnkan kan nibẹ. Ko si jẹ tuntun. Nnkan to tọ ninu ile ijọba niyi teeyan ba ti fẹẹ nipade pọ pẹlu ẹnikẹni ninu awọn mẹta ti wọn wa nibẹ.
“Ti wọn ba n bọ wa fun aṣeyẹ kan, awọn ẹṣọ alaabo DSS gbọdọ mojuto eyi, nigbakuugba ti Aarẹ, Igbakeji Aarẹ tabi iyawo Aarẹ ba ni ṣiṣe kan, nitori awọn araata yoo wa. Ilana ti wọn fi lelẹ fọrọ eto aabo niyẹn.
“Eleyii ko ba Igbakeji Aarẹ wi o. Bawo lẹ ṣe ro pe kofin yẹn de igbakeji Aarẹ tabi awọn minisita?
Tẹ o ba gbagbe, awọn ti wọn ti n gbero lati dije dupo Aarẹ fun ọdun 2023 ni Igbakeji Aarẹ, Yẹmi Ọṣinbajo, igbakeji aarẹ tẹlẹ, Atiku Abubakar, aṣaaju ẹgbẹ oṣelu APC jake-jado ilẹ wa, Aṣiwaju Bọla Ahmed Tinubu, gomina ana n’ipinlẹ Anambra, Peter Obi ati awọn olori ileegbimọ aṣofin Naijiria tẹlẹ, Anyim Pius Anyim, ati Bukọla Saraki.
Awọn mi-in tun ni gomina ipinlẹ Rivers, Nyesom Wike, ojugba rẹ nipinlẹ Ebonyi, Dave Umahi, ti Sokoto ati Bauchi bakan naa, iyẹn Aminu Tambuwal ati Bala Mohammed.
Bakan naa naa lo fiwe pe gomina ipinlẹ Imo nigba kan ri, Rochas Okorocha, minisita fọrọ iṣẹ ati igbanisiṣẹ, Sẹnetọ Chris Ngige atawọn mi-in naa ti wọn ti fi erongba wọn lati dije dupo aarẹ ọdun 2023 di mimọ.

Leave a Reply