Aisun ọdun tuntun lemi ati baba mi ti n bọ tawọn ọlọpaa fi yinbọn pa wọn n’Iwoo – Oluṣẹgun

Florence Babaṣọla

 

 

 

Oluṣẹgun Ọlaoṣebikan fara han niwaju igbimọ tijọba ipinlẹ Ọṣun gbe kalẹ lati ṣewadii iwakiwa awọn ọlọpaa lọjọ Ẹti, Furaidee, ọsẹ yii, nibẹ lo si ti sọ nipa adanu ati akoba nla ti iku baba rẹ mu ba mọlẹbi naa lapapọ.

Gẹgẹ bi Ṣẹgun ṣe wi, “Isin aisun ọdun tuntun 2000 wọ 2001 lemi ati baba mi lọ nileejọsin kan niluu Iwo, nigba ti a n pada lọ sile lawọn ọlọpaa kan n wa mọto bọ lọgangan ibi ti a wa, ti wọn si n yinbọn soke leralera.

“Ka too mọ nnkan to n ṣẹlẹ, ibọn ti ba baba mi lori, wọn ṣubu lulẹ. A gbe wọn lọ sileewosan kan niluu Iwo, latibẹ ni wọn ti dari wa sileewosan Ladoke Akintọla University Teaching Hospital to wa niluu Oṣogbo.

“Awọn marun-un ni wọn wa ninu mọto tawọn ọlọpaa naa lo loru ọjọ yẹn, ṣugbọn Ọlalekan Jimoh nikan ni mo da mọ ninu wọn.

“A bẹrẹ inawo lori baba mi, gbogbo nnkan ini wọn patapata, titi to fi mọ ilẹ-oko ti wọn ni, odidi oṣu mẹfa ni wọn lo ni LAUTECH ka too gbe wọn lọ sile, nibi ti a ti n tọju wọn, amọ, ninu irora ni wọn gbẹmi mi lẹyin oṣu mẹfa.

“Nigba yẹn ẹka Statistics ni mo wa nileewe gbogboniṣe ilu Iree, ṣugbọn nigba ti wahala yii pọ, ti ko si owo kankan mọ, mo kuro nileewe lai pari ẹkọ mi.

“A gbe ẹjọ naa lọ sile-ẹjọ giga ilu Iwo nigba naa, iyẹn lọdun 2002, ṣugbọn nigba tawọn lọgaa lọgaa lẹnu iṣẹ ọlọpaa bẹrẹ si i dunkooko mọ ẹmi wa, la jawọ nibẹ.

“Ṣugbọn ni bayii tigbimọ yii ti wa, mo nigbagbọ pe idajọ ododo yoo fẹsẹ mulẹ. Mo fẹ ki igbimọ yii ba mi paṣẹ fawọn ọlọpaa lati wa awọn to pa baba mi jade, ki wọn si san miliọnu lọna ọgọrun-un naira fun wa gẹgẹ bii owo gba-ma-binu.

Nigba to n gbe idajọ rẹ kalẹ lori ọrọ naa, Adajọ-fẹyinti Akin Ọladimeji to jẹ alaga igbimọ ọhun sọ pe ki awọn agbẹjọro olujẹjọ ati olupẹjọ ṣakojọ gbogbo awijare wọn, ki wọn si ko wọn wa siwaju igbimọ lọjọ kọkandinlogun, oṣu kẹta, ọdun yii.

Leave a Reply