Faith Adebọla, Eko
Lai ka ti pe ọdun mejila l’Abilekọ Rashidat Ogunniyi ti fi wa lọọdẹ ọkọ rẹ bii iyawo, to si ti bimọ mẹta sibẹ, obinrin ẹni ogoji ọdun naa ti rọ ile-ẹjọ pe ki wọn fagi le igbeyawo oun atọkọ rẹ, Kazeem Ogunniyi, o loun o ṣe mọ, kile-ẹjọ tu awọn ka.
Ile-ẹjọ kọkọ-kọkọ to wa lagbegbe Igando, nipinlẹ Eko, ni Rashidat pe ọkọ rẹ lẹjọ si laaarọ Ọjọbọ, Tọsidee, ọsẹ yii, kootu naa ti n ṣalaye ohun toju rẹ ri nile ọkọ, ati idi to fi loun o ṣe mọ.
Rashidat ni ọkọ oun ti fi aja rẹ to n sin rọpo oun, aja naa lo maa n fifẹ han si, oun lo n pọn mọra kiri ile, ko si boya oun atawọn ọmọ jẹun tabi awọn o jẹ, ti aja rẹ ba ṣaa ti yo.
“Ọkọ ati baba ti ko wulo ni Kazeem, ko tiẹ nifẹẹ emi atawọn ọmọ mi rara, ko bikita fun wa mọ.
Nnkan kan ṣoṣo to jẹ ẹ logun ni aja rẹ, aja rẹ lo maa maa fẹ loju fẹ nimu, o ti sọ aja naa di iyawo rẹ, oriṣiiriṣii orin ifẹ lo maa n kọ fun un.
Ọkọ mi ti sọ mi di ẹgusi bara, alupamokuu lo maa n lu mi tori ẹ ba gbona, arijagba ẹda ni, ki i gbọ, ki i gba pẹlu. O fibinu lu mi lọjọ kan to ja mi sihooho goloto loju awọn eeyan, niṣe lo faṣọ ya mọ mi lọrun lọjọ naa, lori ọrọ ti ko to nnkan ni o.
Ẹbẹ ti mo ṣaa fẹẹ bẹ ile-ẹjọ yii ni pe ki wọn tu wa ka, kẹ ẹ si jẹ kawọn ọmọ mi wa lọdọ mi, ki ẹni to fi aja ṣeyawo di aja ẹ mu.” bẹẹ ni olupẹjọ naa rojọ ni kootu.
Ṣugbọn olujẹjọ ko si ni kootu naa, akọwe sọ pe ọpọ iwe lawọn ti fi ranṣẹ si i, ṣugbọn ti ko yọju.
Adajọ kootu naa, Ọgbẹni Adeniyi Kọledoye, paṣẹ pe ile-ẹjọ yoo tun fun olujẹjọ laaafani lati waa ro arojare ẹnu rẹ, eyi lo fi sun igbẹjọ to n bọ si ọjọ kejidinlogun, oṣu Kin-in-ni, ọdun to n bọ.