Aja to bu ọga ọlọpaa jẹ atolowo ẹ dero ahamọ l’Ekoo

Faith Adebọla, Eko

Afaimọ ki baba agbalagba kan, Abayọmi Adeyẹmi, ati Aja rẹ latari bi wọn ṣe lo dẹ aja naa si awọn agbofinro, tiyẹn si bu ọlọpaa-binrin kan jẹ lẹsẹ.

Ojule karundinlọgọfa, ọna Itirẹ, lagbegbe Surulere, nipinlẹ Eko, niṣẹlẹ ọhun ti waye, l’Ọjọruu, Wẹsidee, ọsẹ yii.

ALAROYE gbọ pe Abilekọ Nneka Regina lo mu ẹjọ afurasi ọdaran naa lọ si teṣan ọlọpaa to wa ni Surulere, o lọkunrin naa fẹẹ rẹ oun jẹ, pe oun loun ni ilẹ tọkunrun naa n gbe ori rẹ, o si fẹẹ gba ilẹ ọhun mọ oun lọwọ ni, o lo tun n halẹ mọ ẹmi oun tori ilẹ naa.

N lawọn ọlọpaa ba ṣeto lati lọọ fi pampẹ ofin gbe Abayọmi, ko le waa sọ bọrọ ṣe jẹ ni teṣan, awọn ọlọpaa mẹta ni wọn ran lọ, Inpẹkitọ Atim Umoh lo ṣaaju wọn lọ.

 

 

Ninu alaye ti Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa Eko, Olumuyiwa Adejọbi, ṣe lori ọrọ yii, o ni b’awọn ọlọpaa naa ṣe di ile Abayọmi, ko tiẹ beṣu bẹgba rara, niṣe lo le wọn bii aja, to tun halẹ mọ wọn pe oun maa ṣe wọn leṣe ti wọn o ba kora wọn kuro nile oun. Nibi tawọn ọlọpaa naa ti n gbiyanju ati parọwa s i pe awọn o ba tija wa, ojiji lo tu aja ẹ silẹ, wọn lo paṣẹ fun aja naa pe ko ge awọn jẹ, lawọn ọlọpaa ba bẹ jade.

Ṣugbọn aja mu wọn le, ibi ti wọn si ti n sa lọ laja naa ti deyin mọ  Inpekitọ Umoh lẹsẹ, o bu u jẹ gidi.

Wọn sare gbe Umoh lọ sileewosan aladaani kan nitosi lati tete gba abẹrẹ ajẹsara, lẹyin eyi ni wọn gbe e lọ sileewosan ijọba ni Surulere fun itọju to peye.

Kọmiṣanna ọlọpaa Eko, Hakeem Odumosu, paṣẹ pe ki wọn lọọ gbe Adeyẹmi alaja ati aja rẹ wa. Adeyẹmi ko raaye de ibi ti aja ẹ wa rara ti wọn fi fi pampẹ ọba mu un, wọn si gbe aja naa sinu keeji to wa lẹyin ọkọ awọn ọlọpaa, ni gbogbo wọn ba balẹ si teṣan.

Ṣa, wọn ti taari Adeyẹmi sakata awọn ọlọpaa ọtẹlẹmuyẹ ni Panti, Yaba, ẹsun ti di meji lọrun ẹ, ẹsun ilẹ onilẹ ti wọn lo gba, ati aja to dẹ sawọn ọlọpaa.

Ni ti aja, wọn ti fi sọwọ si ẹka tawọn ọlọpaa to n bojuto aja wa, (Dog Section), ibẹ loun ati olowo ẹ maa gba de kootu, tiṣẹ iwadii ba ti pari, bi Alukoro ọlọpaa ṣe wi.

Leave a Reply