Ajagun-fẹyinti Joṣhua Dongoyaro ti dagbere faye

Faith Adebọla

Ṣe ẹ ranti ọgagun kan to awọn ọmọ orileede yii sọrọ lori redio ati tẹlifiṣan apapọ lọjọ kẹtadinlọgbọn, oṣu kẹjọ, ọdun 1985, nigba ti wọn yẹ aga mọ Ọgagun Muhammadu Buhari nidii, ti wọn si kede Ọgagun Ibrahim Badamọsi Babangida bii olori orileede tuntun? Joshua Dongoyaro lorukọ ọgagun to ṣe ikede ọhun, ṣugbọn o ti doloogbe bayii.

A gbọ pe owurọ Ọjọbọ, Tọsidee yii, lajagun-fẹyinti naa jade laye lẹni ọgọrin (80) ọdun loke eepẹ, ọsibitu Fasiti Jos lo ku si lẹyin aisan ranpẹ.

Ọmọ baba naa, Joseph Dongoyaro, fidi iku baba rẹ ọhun mulẹ, o ni “Dadi mi ti n ṣaarẹ fun bii ọjọ meloo kan nile, nigba ta a si ri i pe ọwọ kinni naa fẹẹ le si i la sare gbe wọn lọ si Jos University Teaching Hospital (JUTH), ki wọn le tọju wọn daadaa.

“Afi bo ṣe di fẹẹrẹ owurọ yii ti iku ti mu wọn lọ. O ya wa lẹnu gan-an. A maa ṣaaro ifẹ ati ọyaya baba agba gan-an. Alatilẹyin gidi ni wọn jẹ fun wa.”

Joseph lawọn ti gbe oku oloogbe naa si mọṣuari ọsibitu ileeṣẹ ologun ofurufu to wa niluu Jos.

Ọjọ kejila, oṣu kẹsan-an, ọdun 1940, ni wọn bi Dongoyaro niluu Taroh, nijọba ibilẹ Langtang, nipinlẹ Plateau.

O ti figbakan jẹ minisita feto aabo labẹ ijọba Oloogbe Sani Abacha, o si wa lara awọn to ditẹ gbajọba lọwọ Ajagun-fẹyinti Muhammadu Buhari lọdun 1985.

Leave a Reply