Ajagun-fẹyinti Ọladipupọ Diya ti ku o

Faith Adebọla

Igbakeji olori orileede wa tẹlẹri, to tun jẹ alakooso gbogbo awọn ọmoogun ori ilẹ lasiko iṣejọba ologun, eyi ti Oloogbe Sani Abacha tukọ rẹ, Ajagun-fẹyinti Ọladipupọ Diya, ti jade laye.

Gẹgẹ bi atẹjade kan tawọn mọlẹbi ọkunrin ẹni ọdun mọkandinlọgọrin naa fi lede laaarọ kutu ọjọ Aiku, Sannde, ọjọ kẹrindinlọgbọn, oṣu Kẹta yii, eyi ti Amofin Oyesinmilọla Diya, buwọ lu lorukọ gbogbo ẹbi, wọn ni idaji ọjọ naa ni baba awọn mi eemi ikẹyin.

Atẹjade naa ka pe: “Lorukọ gbogbo ẹbi Diya nile loko ati loke okun, a kede ipapoda ẹni wa, ọkọ wa, baba wa, baba-agba wa ati ẹgbọn wa ọwọn, Ajagun-fẹyinti-Donaldson Ọladipọ Oyeyinka Diya.

“Ẹni wa ọwọn yii jade laye ni afẹmọju ọjọ kẹrindinlọgbọn, oṣu Kẹta, ọdun 2023 yii.

“Ẹ jọọ, ẹ maa ranti wa ninu adura yin, ba a ṣe n kẹdun oloogbe wa ọwọn yii. A o maa kede awọn eto nipa isinku rẹ lọjọ iwaju.”

Bẹẹ ni atẹjade naa sọ.

Ọladipọ Diya, to ti figba kan jẹ gomina ipinlẹ Ogun, laye ijọba ologun, to si ti di ọpọ awọn ipo nla nla mu lasiko iṣakoso ọhun jẹ ọmọ bibi ilu Odogbolu, nijọba ibilẹ Odogbolu, lagbegbe Ijẹbu, nipinlẹ Ogun.

Ọjọ kẹta, oṣu Kẹrin, ọdun 1944, ni wọn bi i, ọdun 1964 lo bẹrẹ iṣẹ ologun, oun si ṣe igbakeji Sani Abacha laarin ọdun 1993 si 1997, ti wọn fẹyin rẹ ti.

Leave a Reply