Ajalu buruku leleyii o, ṣọja mọkanlegun ti wọn ṣẹṣẹ wọṣẹ ologun ku ninu ijamba ọkọ

Faith Adebọla

Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Jigawa, Lawan Shiisu Adam, ti fidi ẹ mulẹ pe ko din ni mọkanlelogun ninu awọn ṣọja ti wọn ṣẹṣẹ wọṣẹ ologun to padanu ẹmi wọn lojiji ninu ijamba ọkọ to waye lowurọ ọjọ Aiku, Sannde yii, nipinlẹ Jigawa.

Iṣẹlẹ ibanujẹ naa waye loju ọna marosẹ to lọ lati Gwaram si Basirika, nipinlẹ Jigawa, nigba tawọn jagunjagun ọhun n rin irinajo pataki kan lọ sipinlẹ Gombe.

Wọn ni niṣe lọkọ bọọsi ologun tawọn ṣẹṣẹde ṣọja naa wa ṣadeede ya bara kuro loju ọna marosẹ ọhun, nibi biriiji kan to wa lọna naa, to si gbokiti sinu odo to wa labẹ afara naa, gbogbo awọn to wa ninu ọkọ ọhun lo doloogbe.

A gbọ pe wọn ti waa fi ọkọ ti wọn fi n wọ mọto kan fa awoku bọọsi naa jade ninu omi, wọn si ti ko oku awọn ṣọja naa lọọ si mọṣuari ọsibitu ijọba to wa nipinlẹ Jigawa.

Bi Adam ṣe wi, o lawọn maa ṣewadii lati mọ ohun to ṣẹlẹ gan-an ti ijamba naa fi waye.

Leave a Reply