Ajao ji jẹnẹretọ, ni wọn ba fẹẹ dana sun un l’Akurẹ

Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ

Diẹ lo ku ki wọn dana sun ole kan tọwọ tẹ lọsan-an gangan, nibi to ti fẹẹ ji jẹnẹreto gbe lẹgbẹẹ ṣọọbu itaja kan to wa nitosi South Gate, ni fasiti imọ ẹrọ to wa niluu Akurẹ, lọjọ Ẹti, Furaidee, ọsẹ to kọja.

ALAROYE gbọ lati ẹnu ọkan lara awọn araadugbo tiṣẹlẹ naa ti waye pe ọmọkunrin ọhun to porukọ ara rẹ ni Ajao lawọn eeyan kọkọ lu ni alubami, lẹyin eyi lo ni awọn tinu n bi ọhun bẹrẹ si i ko taya ọkọ jọ eyi ti wọn fẹẹ fi dana sun un kawọn agbaagba kan too ba a bẹbẹ, ti wọn si rọ wọn ki wọn fa a le awọn ọlọpaa lọwọ.

Ajao ni wọn ní kó niṣẹ meji tó n ṣe ju ko ja awọn eeyan lole lọ, ọjọ sì ti pẹ diẹ to tí ń ji ẹrọ amunawa awọn onisọọbu to to wa lagbegbe naa, ṣugbọn ti ko sẹni to ri i gba mu lọrun ọwọ ninu gbogbo awọn to n ṣọ ọ.

Awọn agbaagba adugbo to gba a silẹ lọwọ iku ojiji la gbọ pe wọn ṣeto bi wọn ṣe gbe e lọ si tesan ọlọpaa to wa nitosi, nibi ti wọn ti n fọrọ wa a lẹnu wo lọwọ.

 

Leave a Reply