Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ
Oludije lorukọ ẹgbẹ ZLP, Agbọọla Ajayi, naa yege ni Wọọdu keji, ile idibo kẹrin, to wa ni Kiribo, nijọba ibilẹ Esẹ Odo, to ti dibo. Ibo marundin ni irinwo (395) lo ni, nigba ti Akeredolu to tẹle e ni ibo mẹtala, ti Eyitayọ Jẹgẹdẹ ti PDP ni ibo marun-un pere.