Faith Adebọla, Eko
Ajayi Lateef lorukọ, ọmọkunrin ẹni ọdun mọkandinlogun kan, ti wa lakolo ọlọpaa ipinlẹ Eko bayii. Ayederu ibọn lo fi n ja awọn eeyan lole ninu kekẹ Marwa.
Ibọn gidi leeyan maa kọkọ ro pe o mu dani, ṣugbọn ibọn onike tawọn ọmọde fi n ṣere ni, ibọn naa lo si fi n jale l’Ekoo kọwọ palaba ẹ too segi.
Ọgbẹni Olumuyiwa Adejọbi to jẹ Alukoro fun ileeṣẹ ọlọpaa Eko lo sọrọ yii di mimọ ninu atẹjade kan to fi ṣọwọ s’ALAROYE l’Ọjọbọ, Tọsidee, ọsẹ yii. O ni Ọjọruu, Wẹsidee yii, lọwọ tẹ afurasi ọdaran naa lagbegbe Victoria Island, l’Ekoo, nibi to ti n fibọn onike ọhun jale.
A gbọ pe afurasi naa ṣẹṣẹ gba dukia awọn ero inu kẹkẹ Maruwa kan tan ni lọwọ fi ba a. Owo, foonu, aago ọwọ, ṣeeni ọrun atawọn nnkan ẹṣọ ara mi-in, titi dori bata ni wọn lo ti ‘fibọn’ gba lọwọ awọn eeyan.
Adejọbi ni ọkan lara awọn tọkunrin naa ja lole lo ta ileeṣẹ ọlọpaa lolobo, lawọn agbofinro fi dọdẹ rẹ titi ti wọn fi ri i mu, bo tilẹ jẹ pe wọn ko ti i ri awọn ẹru ẹlẹru to ji ko naa gba pada.
Kọmiṣanna ọlọpaa ipinlẹ Eko, Hakeem Odumosu, ti paṣẹ pe ki wọn taari afurasi naa lọ si ẹka awọn ọtẹlẹmuyẹ (CID) ni Panti, Yaba, fun iwadii si i lori iṣẹlẹ yii.
Olumuyiwa fi kun un pe afurasi ọdaran naa ko ni i pẹ ba ara ẹ nile-ẹjọ ti iwadii ba ti pari lori ọrọ re.