Ajẹ niyawo mi, bo ṣe n ba mi ja loju oorun lo n ba mi ja loju aye, mi o fẹ ẹ mọ-Fẹmi

Adefunkẹ Adebiyi, Abẹokuta

Wọn ti pẹ lẹnu ẹjọ naa, kootu yanju ẹ titi, wọn ko ri i sọ, afigba tigbeyawo ọdun mọkandinlọgbọn (29) to da Ọgbẹni Fẹmi Ọlatunde ati iyawo rẹ, Yẹmi, tuka nile-ẹjọ kọkọ-kọkọ Igando, l’Ekoo, lọjọ Iṣẹgun to kọja.

Alagba Ọlatunde ki i ṣe ọmọde mọ, ẹni ọgọta ọdun ni (60). Iyawo to fẹẹ kọ silẹ paapaa ti pe ẹni ọdun mẹrinlelaaadọta (54). Ọmọ marun-un ni ajọṣepọ naa mu jade, gbogbo wọn ni wọn si ti dagba.

Ṣugbọn Ọlatunde ko yee fẹsun kan iyawo ẹ ni gbogbo igba ti igbẹjọ wọn ba waye, ohun to n sọ fun kootu naa ni pe ajẹ ni Yẹmi. Ọkunrin yii sọ pe iyawo oun mu fọto oun lọ sile babalawo, wọn ṣiṣẹ buruku si fọto naa, diẹ lo si ku koun rọ lọwọ atẹsẹ, bi ko ba jẹ aanu toun ri gba ni.

Yatọ si eyi, baale ile naa tun sọ pe iya awọn ọmọ oun aa maa ba oun ja loju ala, oun yoo si ji soju aye bayii, inira yoo mu oun buruku ni. O fi kun un pe loju aye paapaa, iyawo yii ti gbinyanju lati pa oun ri, to jẹ niṣe lo fi majele sounjẹ, boun ti jẹ ounjẹ ọhun tan ni inu rirun bẹrẹ, diẹ lo si ku koun dagbere faye, bi ko ba jẹ pe oun sare lọ si ṣọọṣi ni, nibi ti wọn ti fun oun ni ororo iye mu.

Ole jija tun wa ninu ẹsun ti baba yii fi kan iyawo rẹ, o ni niṣe lo n kọ awọn ọmọ pe ki wọn maa gbe oun lowo. O tilẹ sọ ti ọmọ rẹ ọkunrin kan to gbe ẹgbẹrun lọna igba ataabọ ninu yara oun, bẹẹ, owo iṣẹ ti oun ko ti i ṣe ni.

Gbogbo eyi lo ni o su oun pata, to si yọ ifẹ iyawo ọdun mọkandinlọgbọn naa kuro lọkan oun, afi ki kootu ṣaa pin awọn niya, ki kaluku maa ba tiẹ lọ.

Ṣugbọn iya to fẹsun kan ni ko ri bẹẹ, o ni afarada lo jẹ koun paapaa di asiko yii nile ọkọ oun. Yẹmi ṣalaye bo ṣe jẹ pe Fẹmi le lu eeyan pa, o ni ọrọ ti ko to ọrọ ni i tori ẹ lu oun bii kiku, o ti lu oun bẹẹ to jẹ ọsibitu loun balẹ si.

Itọju awọn ọmọ nkọ, iya ọlọmọ marun-un naa ni ọkọ oun ko ri ti ọmọ ro, ki i gbọ bukaata lori wọn, oun naa loun n daamu lati tọju awọn ọmọ titi ti wọn fi gbọnju. O loun ko fi majele si ounjẹ ẹ, oun ko ran janduku si i lati fiya jẹ ẹ, oun ko si ran awọn ọmọ ẹ lati gbe e lowo o.

Obinrin oniṣowo yii sọ pe ọkọ oun fẹran ko maa toju bọ ile awọn adahunṣe pupọ, ibẹ ni wọn ti n sọ ohun ti ko ṣẹlẹ fun un. O ni ọjọ kan wa toun wọ yara Fẹmi, oku adiẹ loun ba nibẹ, wọn si to abẹla yi i ka.

Aarẹ to lagbara lo ni oun  ba bọ lasiko kan ti ọkọ oun gbe iṣe rẹ de nipa oogun ṣiṣe, o ni asiko kan wa toun ko tiẹ mọ ohun toun n ṣe mọ, bẹẹ, nibi ti Fẹmi ti n toju bọle kiri lo ti fi tiẹ ko ba oun.

Ọrọ olobinrin de nkọ,Yẹmi sọ pe ọkọ oun fẹran obinrin ju, oriṣiiriṣii lo n gbe, ọpọ igba ni ki i sunle pẹlu gẹgẹ bo ṣe wi, o ni otẹẹli oriṣiiṣii to n gbe obinrin lọ lo maa n sun, koda, o pada fẹ ọkan sile ninu awọn ale rẹ ọhun.

Gbogbo alaye ti awọn mejeeji n ṣe fun kootu ree latigba ti ẹjọ wọn ti bẹrẹ, nigba to si jẹ ibi pẹlẹbẹ ni abẹbẹ wọn ṣaa n fi lelẹ, Aarẹ Adeniyi Kọledoye tu wọn ka lọsẹ to kọja yii, o ni ibi ipinya yẹn gan-an ni alaafia wa, nitori o han pe ifẹ ti tan laarin wọn.

Aarẹ Kọledoye paṣẹ pe ki Ọgbẹni Ọlatunde san ẹgbẹrun lọna irinwo naira (400,000) fun iyawo to kọ silẹ naa, ki Yẹmi le ri nnkan bẹrẹ aye rẹ lọtun.

Leave a Reply