Aje o! Reluwee pa maaluu mẹtadinlaaadọta l’Oṣogbo

Florence Babasola, Oṣogbo
Ọkọ reluwee kan to yawọ la gbọ pe o pa maalu mẹtadinlaaadọta ti owo wọn to miliọnu mẹwaa naira niluu Oṣogbo nirọlẹ Ọjọruu, Wẹsidee, ọsẹ yii.
A gbọ pe ipinlẹ Kwara ni reluwee naa n lọ tiṣẹlẹ naa fi ṣẹlẹ lagbegbe Power Line, niluu Oṣogbo.
Eyi to gbẹyin lara awọn koosi (coach) reluwee ọhun to gbe okuta lo deede ya kuro lara odidi ọkọ naa, to si da lulẹ sibi ti awọn maaluu naa ti n jẹ kaakiri, to si pa wọn lọ rẹrẹẹrẹ.
Ọkan lara awọn to ni maaluu naa, Rabiu Ismail, sọ pe ibanujẹ nla niṣẹlẹ naa jẹ fun oun nitori gbogbo maaluu toun ni lo ti ba iṣẹlẹ naa lọ.

Leave a Reply