Ajinigbe meji pade iku ojiji nipinlẹ Ogun

Adefunkẹ Adebiyi, Abẹokuta

Laaarọ kutu ọjọ Abamẹta, Satide, ọjọ kọkanlelogun, oṣu kẹjọ, ni awọn meji ti oku wọn wa nilẹ yii pade iku ojiji.

Ajinigbe to fẹẹ ṣọṣẹ pẹlu awọn yooku ni wọn b’awọn ọlọpaa ṣe wi. Wọn ni inu igbo Bẹrẹ, lagbegbe Onigaari, ni marosẹ Eko s’Ibadan, ni wọn sa si tibọn-tibọn, nibẹ naa ni wọn ti ba awọn ọlọpaa fa a, kiku too pa awọn meji yii ninu wọn.

Irọlẹ ọjọ Satide naa ni Alukoro ọlọpaa nipinlẹ Ogun, DSP Abimbọla Oyeyẹmi, ṣalaye pe awọn kan ni wọn ta kọmandi awọn lolobo pe awọn agbebọn to ṣee ṣe ki wọn jẹ ajinigbe wa ninu igbo Bẹrẹ, wọn ni wọn to mẹfa pẹlu ibọn buruku nni, AK 47 ti wọn gbe lọwọ.

Oyeyẹmi sọ pe kia ni CP Edward Ajogun gbeṣẹ le DPO teṣan Owode-Ẹgba lọwọ, iyẹn CSP Oluṣọla Oniyiku, boun atawọn ikọ ọtẹlẹmuyẹ rẹ ṣe bẹrẹ si i fọ igbo naa kiri niyẹn.

O n’ibi ti wọn ti n ṣe eyi lọwọ lawọn ti wọn fẹẹ mu ti ri wọn, ẹsẹkẹsẹ ni wọn si ti ṣina ibọn bolẹ fawọn ọlọpaa, kia lawọn agbofinro naa si da a pada, ni iro ibọn ba n dun lakọlakọ ni kutukutu owurọ ninu igbo.

Nibi ti wọn ti n yinbọn ọhun ni ajinigbe kan ti ba ogun lọ, ibọn ọlọpaa ba a, o si ku loju-ẹse. Ibọn ba awọn mi-in ninu wọn naa, ṣugbọn wọn ko duro bi Alukoro ṣe wi, o ni wọn gbe ọgbẹ ibọn naa sa lọ ni.

Awọn ọlọpaa bẹrẹ si i wa inu igbo ọhun siwaju, nigba naa ni wọn kan oku agbebọn mi-in ti ibọn ti ba tẹlẹ, n ni wọn ba jẹ meji to ba ogun ọlọpaa lọ.

Wọn ṣi n wa awọn yooku to gbe ọta ibọn sa lọ gẹgẹ bi kọmandi ọlọpaa ṣe wi, bẹẹ ni wọn ni ki awọn ileewosan ma fi akoko ṣofo lati fi to ọlọpaa leti, bi wọn ba ri ẹni to deede gbe ọgbẹ ibọn wa sọdọ wọn lasiko yii fun itọju, nitori o ṣee ṣe ko jẹ awọn amookuṣika to n ṣọṣẹ ninu igbo yii ni.

Ibọn AK47 meji ti nọmba wọn jẹ 1983NF1040 ati 1987-3-CA-1212 ni Oyeyẹmi sọ pe awọn ri gba lọwọ awọn eeyan naa, bẹẹ ni wọn tun ri ọta ibọn marun-un pẹlu.

Leave a Reply