Ajọ OYTMA gbẹsẹ le mọto ijọba ipinlẹ Ọyọ, wọn lo da gosiloo silẹ

Ọlawale Ajao, Ibadan

“Bi gbogbo aye ba n ṣe bayii, a dun”. Eyi lọrọ ti ọpọ eeyan n sọ nigba ti ọga agba ajọ OYTMA, iyẹn, ajọ to n ri si igbokegbodo ọkọ atawọn ohun irinsẹ gbogbo ni ipinlẹ Ọyọ, Mọgaji Akin Fagbemi, fi panpẹ ọba gbe ọkan ninu awọn ọkọ to jẹ ti ajọ naa n’Ibadan.

Ajọ OYTMA yii lo maa n fáìnì awọn awakọ to ba wa mọto gunlẹ sibi ti ko boju mu loju popo ni ipinlẹ Ọyọ, ti wọn si maa n wọ́ iru ọkọ bẹẹ lọ satimọle ninu ọgba ajọ naa to wa ninu sẹkiteriati ijọba ipinlẹ Ọyọ.

L’Ọjọbọ, Tọsidee, to kọja lọkan ninu awọn oṣiṣẹ ajọ naa jaye ta-ni-yoo-mu-mi pẹlu bo ṣe wa mọto to jẹ ti ajọ yii gunlẹ si ibi ti ko yẹ, eyi si da sunkẹrẹ-fakẹrẹ silẹ fawọn mọto atawọn ohun irinsẹ mi-in to n kọja nibẹ laaarọ ọjọ naa.

Iṣẹlẹ yii bọ si asiko ti Mọgaji Fagbemi ti i ṣe alakooso agba fun ajọ OYTROMA n pàráàro kaakiri igboro lati mọ bi awọn eeyan ṣe n tẹle ofin ìwakọ̀gúnlẹ̀ sí.

Lẹsẹkẹsẹ lo paṣẹ pe ki wọn wọ́ ọkọ naa lọ satimọle pẹlu ọkọ nla ti ajọ naa fi maa n wọ awọn ọkọ to ba tapa si ofin.

Bakan naa lo paṣẹ pe ki wọn faini oṣiṣẹ ajọ OYTROMA to wa mọto yii ni iye owo gan-an ti ajọ yii maa n faini awọn araalu to ba ṣẹ si ofin ìwakọ̀gúnlẹ̀.

Nigba to n fidi iṣẹlẹ yii mulẹ, Mọgaji Fagbemi sọ pe gbogbo igba loun maa n kaakiri igboro bẹẹ lati mọ bi awọn awakọ ṣe n pa ofin iwakọgunlẹ mọ si, ati pe gomina ipinlẹ Ọyọ, Ẹnjinnia Ṣeyi Makinde, loun fi iwa naa jọ.

Gẹgẹ bo ṣe sọ, igbesẹ ti mo n gbe wọnyi jẹ diẹ ninu awọn iṣesi ti mo kọ lara Gomina Ṣeyi Makinde. Ọpọ igba lawọn funra wọn maa n jade bẹẹ lati mọ bi gbogbo nnkan ṣe ri nigboro, ṣugbọn aarin oru lawọn (Makinde) maa n jade bẹẹ ni tiwọn, o le jẹ aago meji si mẹta laarin oru.

“Nigba ti Ọlọrun yoo waa ṣe e, nigba ti mo jade lonii, ọkan ninu awọn mọto to jẹ tiwa gan-an lo ko si panpẹ ofin, o si di dandan ka da sẹria to tọ si arufin fun oun naa.”

Leave a Reply