Ibrahim Alagunmu, Ilọrin
Kọmisanna fun ajọ eleto idibo, ẹka ti ipinlẹ Kwara (REC), Malam Garba Attahiru Madami, ti ni ọjọ Abamẹta, Satide, opin ọsẹ yii, ni wọn yoo bẹrẹ si i pin kaadi idibo alalopẹ fun awọn to ṣẹṣẹ forukọ silẹ nipinlẹ naa.
Madami sọrọ yii lasiko to n ba awọn oniroyin sọrọ lọjọ Ẹti, Furaide, ọsẹ yii, niluu Ilọrin nipinlẹ Kwara. O sọ pe awọn to ṣẹṣẹ forukọ silẹ to n lọ bii ẹgbẹrun lọna mẹrinlelogoji (44,000) ni wọn yoo maa tẹwọ gba kaadi idibo alalopẹ wọn lati ọjọ Abamẹta, Satide, ọgbọnjọ, oṣu Kẹrin yii. Awọn to forukọ silẹ laaarin oṣu Kẹfa si oṣu Kejila, ọdun to kọja, nikan ni ọrọ naa kan, ti kaadi wọn si ti wa nilẹ ni ṣẹpẹ. Ki onikaluku lọ sibi to ti forukọ silẹ ko lọọ gba a lati aago mẹsan-an aarọ si aago mẹta irọlẹ.
O fi kun un pe gbogbo ẹni to ba ti to ọmọ ọdun mejidinlogun ti ko ti i forukọ silẹ ni anfaani wa fun lati lọ sori ayelujara lati ṣe bẹẹ, tabi ki wọn lọ si ọfiisi ajọ naa to ba sun mọ wọn ju lọ.
O tẹsiwaju pe iforukọsilẹ miiran ti gbera sọ lati ọjọ kẹtadinlogun, oṣu Kerin, ti yoo si pari ni oṣu Kẹfa, ọdun. O rọ awọn ti ko ti i forukọsilẹ lati tete lo anfaani yii.