Ajọ eleto idibo fun Tinubu niwee-ẹri ‘mo yege’

Jọkẹ Amọri

Ajọ eleto idibo ilẹ wa ti fun aarẹ ilẹ wa ti wọn ṣẹṣẹ dibo yan, Aṣiwaju Tinubu ati igbakeji rẹ, Kashim Shettima, ni iwe-ẹri ‘mo yege’ ninu ibo to waye lọjọ kẹẹẹdọgbọn, oṣu Keji, ọdun yii.

Ni gbọngan International Conference Centre to wa niluu Abuja, nibi ti wọn ti ṣe akojọ esi idibo naa ni eto yii ti waye.

Nigba to n sọrọ lasiko to n gba gba iwe-ẹri naa, Tinubu ni, ‘Ọna si aṣeyọri ta a ṣe yii jin gan-an ni, sibẹ naa, a rin in. Ogun naa le gidi lati ja, sibẹ naa, a ṣegun.’’ O fi kun un pe iwe-ẹri ‘mo yege ti oun gba naa tumọ si pe ko si ọmọ orileede yii kankan ti ko le mu ala rẹ ṣẹ. O ni tọsan-toru loun yoo fi ṣiṣẹ lati mu orileede Naijiria dara si i, o ni itẹsiwaju ati idagbasoke ilẹ Naijiria lo jẹ oun logun.

O ṣeleri pe oun yoo mojuto ọrọ awọn ọdọ ninu ijọba oun, ati pe gbogbo ohun to wa ni ikapa oun loun yoo ṣe lati mu ki Naijiria goke agba si i.

Tinubu lo ni ibo to pọ ju lọ nigba ti wọn ka esi idibo aarẹ to waye lọjọ Satide to kọja ọhun.

Ibo to din diẹ ni miliọnu mẹsan-an (8,805, 420) lo ni, to si fi ibo to din diẹ ni miliọnu meji na alatako rẹ to wa nipo keji, Atiku Abubakar, ẹni to ni ibo miliọnu meje din diẹ (6,984, 290). Oludije ẹgbẹ Labour, Peter Obi, lo wa ni ipo kẹta. Ibo to le diẹ ni miliọnu mẹfa (6, 093,962) loun ni, nigba ti oludije sipo lẹgbẹ oṣelu  New Nigeria Peoples Party wa ni ipo kẹrin.

Bo tilẹ jẹ pe awọn mẹrinla ni wọn dije dupo aarẹ, awọn mẹrin pere ni orukọ wọn hande ju lọ, mẹta ninu wọn lo si ni ibo to jọju.

Ipinlẹ mejila mejila ni awọn oludije mẹta to n ṣiwaju, Bọla Ahmed Tinubu, Atiku Abubakar ati Peter obi ti jawe olubori, nigba ti Rabiu Kwankwazo bori ni ipinlẹ kan pere.

Leave a Reply