Ajọ INEC ke si awọn eeyan ipinlẹ Ọṣun lati wa gba kaadi idibo wọn

Florence Babaṣọla, Oṣogbo

Ni imurasilẹ fun idibo gomina ti yoo waye loṣu to n bọ, ọga agba fun ajọ eleto idibo nipinlẹ Ọṣun, Ọjọgbọn Abdulganiyu Raji, ti sọ pe kaadi idibo to din diẹ ni ẹgbẹrun lọna ojilelọọọdunrun-un (333,179) lo ti wa nilẹ bayii fun awọn oludibo lati gba.
Awọm kaadi idibo naa, gẹgẹ bo ṣe wi, jẹ ti awọn ti wọn ṣẹṣẹ forukọ silẹ, awọn ti aṣiṣe wa ninu akọsilẹ ara kaadi wọn, awọn ti wọn ti sọ kaadi idibo wọn nu ati awọn ti wọn kuro lagbegbe kan bọ si omi-in.
Nigba to n sọrọ nibi eto idanilẹkọọ kan tijọba ipinlẹ Ọṣun pẹlu ifọwọsowọpọ KA Media Consultants, gbe kalẹ fun awọn oniroyin, Raji, ẹni ti olori ẹka to n ri si ọrọ idibo ati amojuto ẹgbẹ oṣelu, Alhaji Shehu Muhammad, ṣoju fun, ṣalaye pe gbogbo awọn kaadi idibo naa lo ti wa ni ọfiisi ajọ INEC kaakiri awọn ijọba ibilẹ.
O fi kun un pe oniruuru eto lo ti wa nilẹ lati pin awọn kaadi naa si awọn ibudo iforukọsilẹ, ko baa le rọrun fun awọn araalu lati gba a.
Ọjọgbọn Raji ni awọn ti ṣafikun ibudo idibo to wa nilẹ tẹlẹ lati ẹgbẹrun mẹta o le mẹwaa si ẹgbẹrun mẹta ati ẹgbẹrin o din diẹ (3,763)
O ke si awọn araalu lati lọọ gba kaadi idibo wọn ko too di asiko idibo ti yoo waye lọjọ kẹrindinlogun, oṣu Keje, ọdun yii, lati le lanfaani lati dibo fun ẹni to ba wu wọn.
Ṣaaju ni Kọmiṣanna feto iroyin ati ilanilọyẹ awọn araalu, Funkẹ Ẹgbẹmọde, ti gboṣuba fun Gomina Oyetọla fun fifọwọ si eto idanilẹkọọ naa.
O ke si awọn oniroyin lati ṣiṣẹ wọn pẹlu otitọ inu lasiko idibo to n bọ, ki wọn si sa fun iroyin to ba le da wahala silẹ laarin ilu.

Leave a Reply