Ajọ INEC kede ọjọ ti wọn gbọdọ kọ orukọ awọn oludije dupo ranṣẹ

Monisọla Saka
Ajo eleto idibo ilẹ wa, INEC, ti kede pe ọjọ kẹtadinlogun, oṣu Kẹfa, ni awọn fun awọn oludije dupo aarẹ di ti wọn gbọdọ forukọ ẹni ti yoo ṣe igbakeji wọn silẹ.
Ajọ yii ṣekilọ pe ẹrọ ayelujara ti wọn yoo lo lati fi orukọ awọn oludije dupo aarẹ atawọn igbakeji wọn silẹ yoo funra rẹ ku ni deede aago mẹfa irọlẹ ọjọ Ẹti, Furaidee, ọjọ kẹtadinlogun, oṣu Kẹfa, ọdun 2022, latari eyi, ẹni to ba pẹ ko ni i ni anfaani lati fi orukọ rẹ sibẹ.
Amọ ṣa o, fun ti ipo gomina atawọn ile-igbimọ aṣofin, ọjọ kin-in-ni si ọjọ kẹẹẹdogun, oṣu Keje, ọdun ta a wa yii, ni wọn yoo ṣe akojọ orukọ wọn sori ẹrọ ayelujara.
Alaga ajọ INEC, Ọjọgbọn Mahmood Yakubu, lo kede eyi nibi ipade oun atawọn igbimọ ajọ eleto idibo l’Ọjọbọ, Tọsidee, niluu Abuja.
Awọn ajọ yii tun tẹnu mọ ọn pe, orukọ awọn to ba jade ninu eto idibo abẹle awọn ẹgbẹ oṣelu gẹgẹ bi abala kẹrinlelọgọrin iwe ofin eleto idibo ṣe la a kalẹ lọdun 2002 lawọn yoo tẹwọ gba.

About Alaroye

Journalist, Press man and News Researcher of the federal Republic of Nigeria

Check Also

Adajọ agba ilẹ wa, Tanko Muhammad ti kọwe fipo silẹ

Adewumi Adegoke Adajọ agba ile-ẹjọ to ga ju lọ nilẹ wa, Onidaajọ Ibrahim Tanko Muhammad, …

Leave a Reply

//lephaush.net/4/4998019
%d bloggers like this: