Ajọ NECO ti sun eto idanwo to n lọ lọwọ si ọjọ mi-in ọjọọre

Ọlajide Kazeem

Ajọ to n ri si idanwo aṣekagba ẹkọ girama, NECO, ti sun eto idanwo ọhun to n lọ lọwọ si ọjọ mi-in ọjọọre, nitori wahala to n ṣẹlẹ kaakiri orilẹ-ede yii.

Ninu ọrọ ti Alukoro ajọ ọhun, Azeez Sanni, fi sita lo ti sọ pe wahala to n ṣẹlẹ kaakiri bayii, ninu eyi ti ijọba lawọn ipinlẹ kan ti kede ofin konile-gbele nitori bi ilu ṣe ri lasiko yii lo mu ajọ naa sọ pe ki idanwo naa ṣi di sisun-siwaju bayii na.

Idi mi-in ti ajọ ọhun tun sọ pe o mu awọn gbe igbesẹ naa ko ju bi gbogbo ileewe lawọn ipinlẹ kan ṣe wa ni titi. Ati pe pupọ ninu awọn ibi to yẹ ki eto idanwo naa ti waye ni ko ṣee ṣe lasiko yii, nitori wahala to n ṣẹlẹ kaakiri.

Igbimọ to n dari ajọ naa ti waa ṣeleri lati tẹ siwaju ni kete ti alaafia ba ti pada saarin ilu. Bẹẹ lo tọrọ aforiji lọwọ awọn obi atawọn akẹkọọ pẹlu awọn mi-in tọrọ kan lori igbesẹ naa.

Leave a Reply