Ajọ NEMA ko awọn ọmọ Naijiria ti wọn ha sorilẹ-ede Libya pada wa sile

Monisọla Saka

L’Ọjọbọ, Tọsidee, ọjọ kẹrinla, oṣu Kẹwaa, ọdun yii, ni ajọ to n ri si iṣẹlẹ pajawiri nilẹ wa, NEMA, ko awọn ọmọ ilẹ yii mẹrindinlaaadoje (126) pada wa siluu Eko lati orilẹ-ede Libya. Ajọ to n ri si wiwọle ati jijade lorilẹ-ede lawọn orilẹ-ede (IOM) lo ṣeto ẹlẹyinju aanu ọhun.

Adele ajọ NEMA niluu Eko, Ibrahim Farinloye, lo sọ eleyii di mimọ fun Ajọ Akoroyin jọ ilẹ wa, (NAN) niluu Eko.

Farinloye ni, lapa ibi ti wọn maa n ko ẹru si ninu papakọ ofurufu Murtala Muhammed, niluu Eko, lawọn ti lọọ pade awọn ọmọ Naijiria naa ninu ọkọ oju ofurufu Al Buraq 700-787, pẹlu nọmba 5A-DMG ti wọn ba pada wale.

Mẹrindinlaaadọta(46) lawọn agbalagba ọkunrin ti wọn wa nibẹ, agbalagba obinrin mejilelọgọta (62), ọmọkunrin kekere meji atawọn ọmọbinrin keekeeke mẹfa, bakan naa lawọn ọmọ ọwọ mẹwaa ba wọn de, mẹrin ninu wọn jẹ obinrin ati ọmọdekunrin mẹfa.

O tẹsiwaju pe pupọ ninu awọn ẹni yii lo jẹ pe niṣe ni wọn tan wọn lọ pe awọn maa ran wọn lọwọ lati re kọja sawọn orilẹ-ede bii Iraq, Egypt, Dubai ati bẹẹ bẹẹ lọ, ṣugbọn ti wọn pada n fi wọn ha sile awọn eeyan kiri nilẹ Libya, ọpọlọpọ ninu wọn lo si n rare kiri niluu oniluu ọhun.

O ni, “A ti ba awọn ero ti wọn dari de ọhun wi, bẹẹ la ba wọn sọ ọpọlọpọ ọrọ lati mọ pe ko si orilẹ-ede to daa ju Naijiria lọ. Oriṣiiriṣii anfaani lo wa fun wa ta a fi le maa gbe igbe aye alaafia ati irọrun pẹlu ibẹru Ọlọrun nilẹ yii lai jẹ pe a n fẹmi ara wa wewu lawọn ilẹ okeere”.

O dupẹ pataki lọwọ ajọ to n ri si iwọle ati ijade lorilẹ-ede Naijiria(NIS), ajọ to n gbalejo awọn ti ko nile(Refugee Commission), ajọ to n ri si ọrọ papakọ ofurufu nilẹ Naijiria (FAAN), ati ileeṣẹ ọlọpaa fun bi wọn ṣe waa fi ifẹ ki wọn kaabọ pada si ilẹ Naijiria.

Leave a Reply