Ajọ WAEC gbẹsẹ le esi idanwo awọn akẹkọọ to jiwee wo lasiko idanwo

Aderohunmu Kazeem

Awọn akẹkọọ bii igba o le diẹ (215,149), ni ajọ to n ṣeto idanwo WAEC ti sọ pe oun ko ni i ti i fun ni esi idanwo wọn bayii.

Ọga agba fun ajọ naa, Patrick Areghan, lo sọrọ yii nipinlẹ Eko nigba to n ba awọn oniroyin sọrọ pe ajọ naa ti ṣetan lati gbe esi idanwo ọhun jade.

Ẹsun ti wọn fi kan awọn ti wọn ko gbe esi idanwo wọn jade ni pe wọn ji iwe wo lasiko ti idanwo ọhun waye.

O ni bii ida mẹtala-o-le (13.98%) ninu awọn ti wọn jokoo ṣe idanwo ọhun ni wọn ko ni i ti i ri esi idanwo ọhun gba latari oriṣiiriṣii ẹsun ti wọn fi kan wọn.

Bakan naa lo sọ pe iwadii ti waye lori ẹsun ti wọn fi kan wọn pe wọn ji iwe wo atawọn ohun mi-in to ṣẹlẹ lasiko idanwo. O ni awọn yoo fi abajade awọn ṣọwọ si igbimọ to yẹ, nibi ti aṣaro yoo ti waye lori ọrọ ọhun. Bẹẹ gẹgẹ lo sọ pe gbogbo awọn ileewe ti ọrọ ba kan pata lawọn yoo kan si.

Akẹkọọ tiye wọn le ni miliọnu kan aabọ ni wọn ṣedanwo ọhun, nigba ti awọn ti wọn le diẹ ni miliọnu kan ṣe daadaa ninu iṣẹ bii marun-un, ninu eyi ti ẹkọ ede oyinbo ati imọ iṣiro ti wa.

O ni apapọ akẹkọọ bii miliọnu kan ati ẹgbẹrun lọna ọọdunrun-o-le diẹ ni wọn ṣe daadaa ninu iṣẹ marun-un, yala wọn jokoo tabi wọn ko jokoo ṣedanwo fun ẹkọ iṣiro ati ẹkọ ede gẹẹsi ninu idanwọ ọhun.

Ọjọ kẹtadinlogun, oṣu kẹjọ ọdun yii ni idanwo ọhun bẹrẹ, ti wọn si kadii ẹ nilẹ lọjọ kejila, oṣu kẹsan-an, ọdun yii

 

Leave a Reply