Akara ti wọn po oogun oloro mọ ni Rhoda ati ọrẹkunrin ẹ n ta fawọn ọmọleewe tọwọ fi tẹ wọn

Faith Adebọla

Egboogi olóró kan ti wọn n pe ni Arizona, ti wọn lo maa n jẹ kori ẹni to ba jẹ ẹ gbona sodi, ni akẹkọọ-binrin tẹ ẹ n wo fọto ẹ yii, Rhoda Agboje, ati ọrẹkunrin ẹ, Ifeanyi Nwankwo, n po mọ akara didun ti wọn ta fawọn ọmọleewe, kọwọ awọn agbofinro too ba wọn niluu Abuja.

Agbẹnusọ fun ajọ NDLEA, iyẹn ajọ to n gbogun ti lilo, mimu, gbigbe ati ṣiṣe okoowo egboogi oloro nilẹ wa, Ọgbẹni Fẹmi Babafẹmi, lo ṣalaye bẹẹ lọjọ Iṣẹgun, Tusidee yii, pe ọjọ Aje, Mọnde ọsẹ yii, lawọn ẹṣọ ajọ naa fi pampẹ ofin gbe Rhoda, ti wọn lo wa ni ipele kẹta ẹkọ rẹ ni Fasiti Abuja, lẹyin ti olobo ti ta wọn nipa akara oloro to n ta fawọn ọmọleewe keekeeke, wọn lo tun n ta a fawọn araalu pẹlu.

Akẹkọọ kan ni wọn lafurasi ọdaran yii fun ni akara ọhun jẹ lọjọ mẹta ṣaaju asiko ti wọn mu un, bọmọ ọhun ṣe jẹ akara tan ni wọn lo bẹrẹ si i ṣe wanranwanran, to n sọrọ lodilodi, ko le sun, ara ẹ o si balẹ.

Pẹlu ibẹru lawọn obi ọmọ naa fi mu un lọọ sọsibitu ijọba, lawọn dokita ba ṣe ayẹwo fun un, ayẹwo si fi han pe ọmọ ọhun ti jẹ ohun to lagbara ju ọpọlọ ẹ lọ ni, wọn ni egboogi oloro lo jẹ.

Eyi lo mu ki wọn tẹ ọmọbinrin naa ninu lẹyin ọpọ wakati nigba tara ẹ balẹ, lọmọ ba jẹwọ fun wọn pe Aunti Rhoda lo fun oun lakara jẹ. Ọrọ di tọlọpaa, atọdọ ọlọpaa lọrọ gba de ọdọ awọn ẹṣọ NDLEA (Natiọnal Drug Law Enforcement Agency), ẹka ti Abuja, awọn ni wọn bẹrẹ si i finmu finlẹ, ti wọn fi ri Rhoda mu lagbegbe Ẹsiteeti NNPC Cooperative, nitosi Ẹsiteeti Gaduwa, niluu Abuja.

Nigba ti wọn beere bọrọ ṣe jẹ lo jẹwọ fun wọn pe oun ati ọrẹkunrin oun, Ifeanyi Nwankwo, lawọn jọ n taja buruku ọhun. O ni Ifeanyi atọrẹ ẹ mi-in tiyẹn ti sa lọ bayii ni wọn maa n ṣeto egboogi oloro tawọn maa n po mọ eroja akara ti wọn n ta ọhun.

Kọmanda ajọ NDLEA, ẹka ti Abuja, sọ pe nigba tawọn ṣayẹwo kẹmika oloro ti wọn n lo naa, wọn ri i pe awọn eroja ọti ogogoro ati igbo lo wa ninu ẹ.

Wọn lawọn afurasi mejeeji ọhun jẹwọ pe ẹgbẹrun kan aabọ naira (N1,500) lawọn n ta akara mẹta, wọn si ba akara to le ni igba (200) nile Ifeanyi, lẹyin tọwọ tẹ ẹ.

Ṣa, wọn ni iwadii ṣi n tẹsiwaju, bẹẹ lawọn agbofinro ti n tọpasẹ awọn to ku nidii okoowo akara oloro yii, wọn ni gbogbo wọn ni wọn maa fimu kata ofin laipẹ.

Leave a Reply