Akeem ọlọkada to ta tẹtẹ lawin l’Oṣogbo ti foju bale-ẹjọ

Florence Babaṣọla, Oṣogbo

Ọmọkunrin ọlọkada kan, Akeem Jimoh, lawọn ọlọpaa ti wọ lọ si kootu Majisreeti kan niluu Oṣogbo lori ẹsun pe o ta tẹtẹ lawin lọjọ kejila, oṣu kẹjọ, ọdun yii.

Ipinlẹ Ondo ni Akeem ti wa gẹgẹ bi agbefọba, Inspẹkitọ Kayọde Adeoye, ṣe sọ, ọdun Ileya lo si waa ṣe l’Oṣogbo. Nigba to kọkọ de, o ta tẹtẹ Betnaija, o si jẹ ẹgbẹrun lọna igba naira (#200,000).

Ṣugbọn lẹyin iyẹn ni ẹkọ ko ṣoju mimu fun Akeem mọ, o na gbogbo owo ọwọ rẹ tan, o si bẹrẹ si i ta tẹtẹ lawin.

Lọjọ kan ṣoṣo, o ta tẹtẹ awin titi de ẹgbẹrun lọna aadọjọ naira (#150,000) lọdọ Ayanlọla Tobilọba lagbegbe Ayetoro, o si tun lọ sọdọ Adigun Saheed, nibi to ti ta tẹtẹ ẹgbẹrun lọna ọgọrun -un naira (#100,000) lagbegbe Oke-Baalẹ.

Akeem sọ ni kootu pe oun jẹbi ẹsun meji ti wọn fi kan an.

Adajọ ile-ẹ̣̣̣jọ Majisreeti naa, Adebayọ Ajala, ni bo tilẹ jẹ pe Akeem sọ pe oun jẹbi ẹsun ti wọn fi kan an, o pọn dandan lati fidi rẹ mulẹ pe ọkan lara awọn ẹsun naa ko lẹsẹ nilẹ nitori pe iṣẹ to ni atilẹyin ofin ni Betnaija, awọn ọlọpaa ko gbọdọ sọ pe iṣẹ naa lodi si ofin.

Nitori idi eyi, adajọ sọ pe yala ki wọn fi olujẹjọ pamọ satimọle awọn ọlọpaa tabi ki wọn fun un ni beeli titi digba ti wọn yoo tun gbe e wa sile-ẹjọ lori ẹsun mi-in

Leave a Reply