Akẹkọọ fasiti Al-Hikmah lẹdi apo pọ pẹlu agunbanirọ lati ja ileewe naa lole miliọnu mẹsan-an naira

Stephen Ajagbe, Ilorin

Akẹkọọ kan to wa nipele 400Level, ni fasiti Al-Hikmah, niluu Ilọrin, Idris Shuaibu Suleiman ati agunbanirọ kan to sin ijọba nipinlẹ Jigawa, Nazim Usman Gomna, lajọ EFCC wọ lọ sile-ẹjọ l’Ọjọbọ, Tọsidee, ọsẹ yii, lori ẹsun pe wọn lẹdi apo pọ lati ja ileewe naa lole miliọnu mẹsan-an naira.

Afurasi mejeeji ni wọn wọ lọ siwaju Adajọ Sikiru Oyinloye, tile-ẹjọ giga ipinlẹ Kwara to fikalẹ silu Ilọrin.

Idris ati Nazim ni wọn fẹsun kan pe wọn fọgbọn jibiti wọ ori ikanni ayelujara ileewe Al-Hikmah lati wọ owo ileewe tawọn akẹkọọ ba san sinu akanti wọn.

Nazim to jẹ akẹkọọ-jade nipa imọ kọmputa ni wọn lo n bawọn ro idan naa lori ẹrọ ayelujara, o lo akanti Idris to jẹ akẹkọọ ni fasiti naa lati maa fi gba owo to yẹ ko lọ sinu apo ileewe naa sapo ara wọn.

Akọsilẹ EFCC ṣalaye pe laarin oṣu kẹta si ikarun-n, ọdun 2020, lawọn mejeeji wuwa ọdaran naa.

Nigba tile-ẹjọ ka ẹsun wọn si wọn leti, awọn mejeeji lawọn ko jẹbi.

Agbẹjọro EFCC, Sẹsan Ọla, rọ ile-ẹjọ lati gba wọn sahaamọ ọgba ẹwọn titi di ọjọ tigbẹjọ yoo bẹrẹ.

Ṣugbọn, Amofin A.T Kamaldeen ati Ismail Mustapha to ṣoju awọn olujẹjọ naa bẹ ile-ẹjọ lati gba oniduuro awọn onibaara wọn.

Adajọ Oyinloye gba beeli ọkọọkan ni miliọnu mẹta aabọ naira ati oniduuro kọọkan niye kan naa.

Adajọ ni oniduuro naa gbọdọ maa gbe ilu tile-ẹjọ naa wa, onitọhun yoo fi nọmba ẹrọ ibanisọrọ rẹ ati adirẹsi ile to n gbe silẹ, yoo si tun ko aworan pelebe rẹ kalẹ fun ile-ẹjọ.

Bakan naa, ile-ẹjọ paṣẹ fun awọn olujẹjọ naa lati ko iwe-irinna wọn kalẹ, wọn ko si gbọdọ lọ si irinajo kankan lai gba aṣẹ ile-ẹjọ titi tẹjọ naa yoo fi pari. O ni wọn gbọdọ maa yọju sile-ẹjọ ni gbogbo ọjọ tigbẹjọ wọn ba waye, bi bẹẹ kọ wọn yoo padanu anfaani beeli toun fun wọn.

Leave a Reply