Akẹkọọ Fasiti Bowen jẹ ẹbun ọkọ ayọkẹlẹ ninu idije arokọ tijọba ipinlẹ Ọṣun ṣe

Florence Babaṣọla

Mọto Toyota Corolla ni akẹkọọ kan to wa ni ẹka imọ iṣegun ni Fasiti Bowen, niluu Iwo, Adeyẹmọ Victor Ayọdeji, fi ṣefa jẹ lẹyin to perege ninu arokọ ayajọ ọjọ Ominira orileede Naijiria ti ijọba ipinlẹ Ọṣun ṣagbekalẹ rẹ.

Ọdun to kọja ni eto naa bẹrẹ lati fi ṣe koriya fun awọn akẹkọọ nileewe girama ati ile-ẹkọ giga kaakiri ipinlẹ Ọṣun, ṣugbọn ẹbun ọkọ ayọkẹlẹ ti wọn fi ti i nidii lọdun yii tun jẹ ko jẹ ara ọtọ.

Nnkan bii oṣu kan sẹyin nijọba, nipasẹ ileeṣẹ to n ri si ọrọ akanṣe iṣẹ ati ibaṣepọ ẹlẹkunjẹkun, ti fi ikede sita lori koko (topic) ti awọn akẹkọọ ti wọn ba nifẹẹ si eto naa yoo kọ arokọ le lori.

Lẹyin ti awọn akẹkọọ naa fi iwe kalẹ ni wọn ko awọn igbimọ ọlọpọlọ pipe jọ, ninu eyi ti a ti ri Dokita Lasisi Ọlagunju, Ọgbẹni Fẹmi Ọlanipẹkun, Dokita Temitọpẹ Akintunde, Dokita Fọlọrunsọ Ladapọ ati Dokita Yesooro Ọlọṣọ wa.

Awọn ni wọn ṣayẹwo akọsilẹ awọn akẹkọọ yii, bẹẹ ni wọn tun ko wọn jọ lati sọrọ lori awọn koko naa, lẹyin eyi ni wọn si kede orukọ awọn to yege.

Adegboyega Abisola Faith lati ileewe Fakunle Comprehensive High School, Osogbo, lo ṣe ipo kin-in-ni ni ẹka ileewe girama, Ọlaniyi Inioluwa Ọpẹyẹmi lati Ambassadors College, Ile-Ife, lo ṣe ipo keji, nigba ti Onwugbofor Happiness lati Our Lady and St. Francis College, niluu Oṣogbo, wa ni ipo kẹta.

Adeyẹmọ Victor Ayọdeji ti Fasiti Bowen, niluu Iwo, lo wa ni ipo kin-in-ni ni ẹka awọn ile-ẹkọ giga, Ayọọla Victor Oluwagbemiga lati Yunifasiti Ibadan lo ṣe ipo keji, nigba ti Ademuyi Stella Jesuloluwa lati Adeleke University, Ẹdẹ wa ni ipo kẹta.

Ninu ọrọ rẹ, Gomina Oyetọla, ẹni ti Igbakeji rẹ, Benedict Alabi, ṣoju fun nibi eto naa sọ pe iṣejọba oun nigbagbọ pe ti amojuto to peye ba ti wa fun awọn akẹkọọ, alaafia ati isinmi pipe yoo wa fun ipinlẹ Ọṣun lọjọ iwaju.

O ni eto naa wa lati jẹ ki ironu awọn ọdọ naa wulo fun igbega orileede Naijiria, yatọ si awọn ọna ti ko bojumu ti ọpọlọpọ wọn n lo ọgbọn-ori wọn si lasiko yii.

Oyetọla ṣeleri pe iṣejọba oun yoo maa tẹsiwaju ninu oniruuru awọn eto bẹẹ fun awọn ọdọ nitori awọn ni ogo orileede Naijiria.

Bakan naa ni Kọmiṣanna fun ọrọ iṣẹ akanṣe ati ibaṣepọ ẹlẹkunjẹkun, Ọnarebu Lekan Badmus, dupẹ pupọ lọwọ gomina fun bi ko ṣe kaaarẹ ninu igbelarugẹ awọn ọdọ kaakiri ipinlẹ Ọṣun.

Badmus ṣalaye pe iwuri lo jẹ lati ri i pe awọn akẹkọọ bii ẹẹdẹgbẹrin ni wọn kopa ninu arokọ naa kaakiri awọn ileewe aladaani ati tijọba bii mẹrinlelọgbọn lorileede yii.

O ni erongba eto naa ni lati jẹ ki awọn akẹkọọ yii tubọ nifẹẹ si iwe kika ati kikọ lọna ti wọn yoo fi maa ronu jinlẹ ninu ohun gbogbo to n lọ lorileede Naijiria, ti yoo si maa mura lọdọọdun lati fakọyọ.

Racheal Adebimpe Ṣowade Foundation lo gbe ọkọ ayọkẹlẹ naa pẹlu oniruuru awọn mi-in kalẹ fun ẹni to fakọyọ, nigba tijọba ipinlẹ Ọṣun atawọn eeyan mi-in naa gbe ẹbun owo nla kalẹ fun awọn oloriire ọmọ naa.

Leave a Reply