Akẹkọọ Fasiti Ifẹ: Adajọ ni Adedoyin atawọn oṣiṣẹ rẹ lẹjọ lati jẹ

Florence Babaṣọla, Oṣogbo

Adajọ ile-ẹjọ giga ipinlẹ Ọṣun, Onidaajọ Adebọla Adepele Ojo, ti sọ pe Dokita Rahman Adedoyin atawọn oṣiṣẹ rẹ mẹfa ni ẹjọ lati jẹ lori ẹsun iku Timothy Adegoke ti wọn fi kan wọn.

Adedoyin lo ni ileetura Hilton, niluu Ileefẹ, nibi ti akẹkọọ Fasiti Ifẹ kan, Timothy Adegoke, ku si loṣu kọkanla, ọdun to kọja.
Ṣaaju ni awọn agbẹjọro ti wọn n gbẹnu sọ fun awọn olujẹjọ mejeeje ti sọ pe awọn onibaara awọn ko lẹjọ lati jẹ nitori ko si eyi to jẹrii kankan to ni i ṣe pẹlu wọn laarin awọn ẹlẹrii mẹjẹẹjọ ti awọn olujẹjọ pe.

Ninu idajọ rẹ laaarọ Ọjọbọ, Wẹsidee, ọsẹ yii, Onidaajọ Ojo sọ pe awọn mejeeje ni ẹjọ lati jẹ lori ọrọ naa. O ni ki i ṣe pe oun sọ pe wọn jẹbi ẹ, ṣugbọn wọn kan ni lati sọ tẹnu wọn lori ohunkohun ti wọn ba mọ lori ẹsun mọkanla ti wọn fi kan wọn lọtọọtọ.
Nitori naa, gbogbo awọn agbẹjọro abala mejeeji fẹnu ko pe ki awọn olujẹjọ bẹrẹ awijare wọn lọjọ kẹẹẹdọgbọn, oṣu Kẹrin ọdun yii.

Leave a Reply