Akẹkọọ FUNAAB ti wọn ji gbe ti gba itusilẹ

 Adefunkẹ Adebiyi,Abẹokuta

 Nathaniel Toyinbo Ọlayinka, akẹkọọ ileewe imọ ọgbin, FUNAAB, ti wọn ji gbe labule Itoko, l’Ọdẹda, ti gba itusilẹ. Alẹ ọjọ Aje, Mọnde, ọsẹ yii, ni wọn yọnda akẹkọọ onipele kẹrin naa pẹlu awọn meji mi-in ti wọn jọ ji wọn gbe.

 DSP Abimbọla Oyeyẹmi, Alukoro ọlọpaa nipinlẹ Ogun, fidi itusilẹ yii mulẹ, bẹẹ lo ni awọn ti awọn ajinigbe gbe sa lọ laaarọ ọjọ Satide to kọja yii naa ti wa pẹlu awọn eeyan wọn.

 Ko sọrọ nipa boya awọn ajinigbe yii gbowo ki wọn too fi wọn silẹ, ṣugbọn o ni lati ọjọ ti wọn ti ji awọn mẹta naa gbe lawọn ọlọpaa ti wa ninu igbo, ti wọn n wa awọn ajinigbe naa kiri ko too di pe wọn ri Toyinbo, Dominic to ni oko ti wọn ti ji wọn gbe ati ọmọ Togo to ṣikẹta wọn.

 

Leave a Reply