Akẹkọọ ki olukọ rẹ mọlẹ ni Fasiti Ilọrin, o lu u bii aṣọ ofi

Ibrahim Alagunmu, Ilọrin

Ọjọbọ, Tọsidee, ọṣẹ to kọja yii, ni akẹkọọ Fasiti Ilọrin, nipinlẹ Kwara, Captain Walz, lu olukọ rẹ, Arabinrin Zakariya, lalubami, fẹsun pe olukọ naa kọ lati ran an lọwọ lori ọrọ SIWẸSI ti ko ṣe, ti olukọ naa si ti wa lẹsẹ-kan-aye ẹṣẹ-kan-ọrun bayii.

ALAROYE gbọ pe akẹkọọ ọhun ti ọpọ eeyan mọ si Captain Walz, ni wọn fẹsun kan pe ko ṣe SIWẸSI, to pan dandan fun gbogbo akẹkọọ lati ṣe ni ẹka rẹ, to si n wa iranwọ awọn olukọ naa, ṣugbọn ti wọn o ṣetan lati ran an lọwọ. O pinnu lọkan rẹ pe oun yoo fi oju awọn olukọ ọhun ri mabo. Alẹ Ọjọruu, Wẹsidee, lo gbera lọ silẹ olugbani nimọran ni lẹburu wọn (L. A), o n gba geeti mọ ọn lori, ṣugbọn iyẹn ko si geeti. Owurọ Ọjọbọ, Tọsidee, lo gba inu ọgba ileewe Fasiti Ilọrin lọ, o lọọ ba olukọ to n bojuto iṣẹ akanṣe rẹ, iyẹn Arabinrin Zakariya,

lọọfiisi rẹ, lo ba bẹrẹ si lu u bii aṣọ ofi, Ileewosan olukọni Fasiti Ilọrin ni olukọ naa wa bayii, to si wa lẹsẹ-kan-aye, ẹsẹ-kan-ọrun. Awọn ẹṣọ alaabo inu ọgba Fasiti Ilọrin ti mu akẹkọọ naa, ti wọn si ti fa a le ọlọpaa lọwọ.

Leave a Reply