Akẹkọọ MAPOLY gbadajọ ẹwọn, nitori jibiti ori ayelujara

Adefunkẹ Adebiyi, Abẹokuta

 Oṣu meje gbako ni Adebọwale Babatunde Ismail, ẹni ọdun mẹrinlelogun, to jẹ akẹkọọ nileewe giga Moshood Abiola Polytechnic (MAPOLY), l’Abẹokuta, yoo fi ṣẹwọn, nitori jibiti onimiliọnu to lu oyinbo kan lori ayelujara.

Ọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọjọ kẹjọ, oṣu keji, ọdun 2022 yii, ni Adajọ Uche Agomoh, ti ile-ẹjọ giga ilu Ibadan, nipinlẹ Ọyọ, paṣẹ pe ọmọ to n kẹkọọ nipa ẹrọ kọmputa ni MAPOLY ọhun gbọdọ ṣẹwọn, bẹẹ lo si gbọdọ da miliọnu kan ati ẹgbẹrun lọna irinwo Naira ( 1,400,000) to feru gba lọwọ oyinbo pada

 Nigba tawọn EFCC to mu Adebọwale n ṣalaye nipa ẹ fun kootu, aṣoju wọn sọ pe pipe ara ẹni loun ti a ko jẹ lati gbowo lọwọ ẹnikeji lẹṣẹ ti ọmọkunrin naa ṣẹ.

O ni Adebọwale paarọ orukọ ẹ lẹka ayelujara to ti lu oyinbo torukọ ẹ n jẹ John Dauherty, ni jibiti, orukọ to n jẹ ni Annabel Torrens.

Adirẹẹsi kan ti i ṣe dsprinklse@gmail. com lo fi n lu oyinbo yii ni jibiti pẹlu awọn ọrọ to fi n ranṣẹ si i.

Pipe ara ẹni loun ti a ko jẹ yii lodi labẹ ofin, o si ni ijiya ninu bi kootu naa ṣe wi.

Wọn beere lọwọ Adebọwale pe ṣe o gba pe oun jẹbi ẹsun naa tabi bẹẹ kọ, ẹsẹkẹsẹ lo dahun pe oun jẹbi, loootọ loun ti gbá oyinbo, toun ti fowo rẹ ṣe faaji ara oun .

Eyi ni Adajọ Agomoh ṣe ju u sẹwọn oṣu meje, to tun paṣẹ pe ko da owo to feru gba pada, ko si yọnda ọkọ ayọkẹlẹ Toyota Rav 4 to fi n jaye, pẹlu foonu nla ti i ṣe iPhone 11 pro to wa lọwọ ẹ

Leave a Reply