Akẹkọọ meji ku lẹyin ti wọn lo oogun aran fun wọn nileewe l’Ogun

Adefunkẹ Adebiyi,Abẹokuta

Lọsẹ to kọja yii ni ijọba ipinlẹ Ogun bẹrẹ eto fifun awọn akẹkọọ ileewe alakọọbẹrẹ to jẹ tijọba nipinlẹ yii loogun aran gẹgẹ bii iṣe rẹ. O kere tan, awọn ọmọde ẹgbẹrun lọna ẹẹdẹẹgbẹrin (700, 000) ni wọn lawọn yoo fun loogun naa, ṣugbọn meji ninu awọn akẹkọọ naa dero ọrun lojiji lẹyin ti wọn lo oogun ọhun tan, lọrọ ba dohun tawọn obi n sọ pe oogun aran naa lo fa iku awọn ọmọ yii.

Awọn ọmọ meji to ku naa ni, Ọmọlaṣọ Kẹyẹde; ọmọ ọdun mẹjọ to wa ni pamari tuu, iwe keji, ati Ẹniọla Oyeyẹmi; ọmọ ọdun mẹsan-an toun wa niwee kẹrin nileewe St. James African Church, to wa ni Idi-Apẹ, tawọn mejeeji jọ n lọ l’Abẹokuta.

Ohun ti AKEDE AGBAYE gbọ ni pe ọjọ Iṣẹgun ọsẹ yii ti i ṣe ọjọ kẹtadinlogun, oṣu kọkanla, ni awọn tiṣa fun awọn ọmọde meji yii loogun aran naa lo, gẹgẹ bi wọn ṣe fun awọn yooku wọn naa ti nnkan kan ko si ṣe awọn iyẹn.

Koda, wọn ti kọkọ kọwe le wọn lọwọ lọjọ Aje, Mọnde, ọsẹ naa, pe ki wọn sọ fawọn obi wọn nile pe ijọba ti paṣẹ pe kawọn fun wọn loogun aran, awọn yoo si fun wọn lọjọ keji ti i ṣe Tusidee.

Ni ti Kẹyẹde, Aunti rẹ to ba awọn akọroyin sọrọ l’Abẹokuta lẹyin iku ọmọ naa, Abilekọ Oluwatosin Nasiru, ṣalaye pe awọn ko fẹ ki wọn fun Kẹyẹde loogun naa, iyẹn ni aburo oun kan ṣe lọọ sọ fun wọn nileewe naa laaarọ ọjọ Iṣegun pe ki wọn ma fun un, nitori o maa n ṣe bakan lara rẹ to ba lo oogun aran.

Ṣugbọn tiṣa Kẹyẹ ko gba ikilọ gẹgẹ bi Abilekọ Nasiru ṣe wi. O ni o fun ọmọ naa loogun ọhun lo, ọmọ loun ko fẹ, ṣugbọn tiṣa naa lu u, o si fi agidi lo o fun un.

Koda, wọn ni Kẹyẹde bi oogun naa pada, ṣugbọn tiṣa rẹ tun lu u, o si fun un ni omi-in pe ko lo o, bo ṣe lo o niyẹn to si bẹrẹ si i bi, latigba naa lọ, titi to fi dele, ni ko si yee bi.

Wọn gbe e lọ sọsibitu Apata-Iye to wa ni Odo-Ọyọ, l’Abẹokuta, ṣugbọn Kẹyẹ dagbere faye laaarọ Wẹsidee, ọjọ kejidinlogun, oṣu yii.

Ọrọ Ẹniọla naa ko fi bẹẹ yatọ, oun naa loogun yii tan ni wọn lo bẹrẹ si i bi. Wọn gbe oun naa lọ sileewosan kan naa ti wọn gbe Kẹyẹde lọ ( agbegbe kan naa ni wọn n gbe l’Opopona Ademọla, Idi-Apẹ), ṣugbọn Ọjọruu loun paapaa jade laye.

Lati fidi ẹ mulẹ pe ki i ṣe oogun ti wọn lo nileewe naa lo pa wọn, ikọ onimọ ilera lati ileeṣẹ eto ilera nipinlẹ Ogun ṣabẹwo sile awọn ọmọ mejeeji yii, wọn si lawọn yoo ṣayẹwo si oku wọn lati mọ ohun to pa wọn.

Awọn eeyan Kẹyẹde ti sin in ni tiẹ, wọn lawọn ko fara mọ ki wọn hu oku ẹ fun ayẹwo, ṣugbọn wọn ko ti i sin Ẹniọla lasiko ti a n kọ iroyin, o si daju pe wọn yoo ṣe ayẹwo naa fun oku rẹ lati mọ ohun to pa a gan-an.

Kọmiṣanna eto ilera nipinlẹ Ogun, Dokita Tomi Coker, ṣalaye ninu atẹjade kan to fi sita lori iṣẹlẹ yii pe asiko ẹẹrun la wa, awọn aisan onigbameji (Kọlẹra), atawọn mi-in ti wọn maa n waye nigba ọgbẹlẹ wa lasiko yii, o ni o ṣee ṣe ko jẹ ohun to pa awọn ọmọde naa niyẹn.

Kọmiṣanna ṣalaye oun naa lo ninu oogun aran yii, kinni kan ko ṣe oun, bẹẹ naa si lọpọlọpọ ọmọ lo o kaakiri awọn ileewe nipinlẹ yii, kinni kan ko ṣe wọn lẹyin rẹ.

Coker sọ pe Kọlẹra lo pa awọn ọmọ meji yii, oogun aran kọ rara. O ni kawọn eeyan ṣọra fun arun yii, ki wọn maa wa ni imọtoto ni gbogbo igba, ki wọn si maa fọwọ wọn deede.

Ṣugbọn awọn eeyan agbegbe naa lawọn ko fara mọ ohun ti ijọba sọ, wọn ni omi kanga tawọn n mu mọ daadaa, oun kọ lo fa iku awọn ọmọde meji naa gẹgẹ bijọba ṣe wi.

Wọn ni awọn ko ṣẹṣẹ maa mu omi naa, awọn ọmọ yii paapaa ko ṣẹṣẹ maa mu un, o ṣe jẹ igba ti wọn lo oogun aran fun wọn ni wọn ko si wahala.

Ṣa, nigba ti esi ayẹwo ti wọn ba ṣe fun oku Ẹniọla Oyeyẹmi  ba jade, ohun to fa iku naa yoo fẹsẹ mulẹ gidi.

 

Leave a Reply