Ọlawale Ajao, Ibadan
Ti wọn ba n ṣadura pe ki Ọlọrun ma ṣe jẹ ka ba ibi ta a gba waye pada sọrun, ohun ti wọn gba lero pẹlu adura pataki ọhun lo ṣẹlẹ n’Ibadan laipẹ yii, nibi ti akẹkọọ ile-ẹkọ giga kan ti padanu ẹmi ẹ ni kete ti oun pẹlu obinrin akẹkọọ ẹgbẹ ẹ kan jọ ba ara wọn laṣepọ tan.
Akẹkọọ The Polytechnic, Ibadan, ọhun, torukọ ẹ n jẹ Ọrọmidayọ, pẹlu ọrẹbinrin ẹ to n jẹ Aramide la gbọ pe wọn jọ lo oogun amarale lasiko ibalopọ, eyi to fun awọn mejeeji lagbara buruku lati ṣe ere egele naa fun ọpọlọpọ asiko laisimi.
ALAROYE gbọ pe agbara aramọnda ti oogun naa fun wọn ni ko jẹ ki awọn mejeeji mala wahala ti wọn n fi ara wọn ṣe titi ti ọrọ naa fi bẹyin yọ fun wọn.
Ẹmi awọn mejeeji ti n bọọ lọ to bẹẹ to jẹ niṣe ni wọn kan n wo ara wọn loju lasan, nitori ti wọn ko lagbara lati ṣe ohunkohun mọ.
Awọn alabaagbe ọmọkunrin naa lo fipa jalẹkun wọle lọọ wo wọn nigba ti wọn ko ri i ki wọn jade sita lẹyin ọpọlọpọ wakati, ti wọn ko si tun gburoo wọn ninu ile.
Nigba ti awọn eeyan wonyi wọle, oku Ọrọmidayọ ni wọn ba gbalaja lori ibusun, Aramide ololufẹ ẹ paapaa ko si jẹ ara aye, bẹẹ ni ko jẹ ero ọrun.
Akẹkọọ ọlọdun keji, nipele ọjẹ wẹwẹ ni wọn pe Ọrọmidayọ lẹka ẹkọ imọ ẹrọ ni Poli Ibadan, nigba ti Aramide jẹ akẹkọọ ọlọdun keji bakan naa lẹka imọ nipa iṣakoso ileeṣẹ nileewe ọhun.
Lẹyin ti wọn ti ileewe de nirọlẹ ọjọ Aje, Mọnde, ọsẹ yii, la gbọ pe iṣẹlẹ to da ẹmi wọn legbodo ọhun waye.
Gẹgẹ bi ọkan ninu awọn alabaagbe oloogbe naa ṣe fidi ẹ mulẹ, “ana lo yẹ ka bẹrẹ idanwo wa ko too di pe wọn fagi le e. Lẹyin ti awọn mejeeji ti sukuu de ni wọn jọ wa sile waa ba ara wọn laṣepọ lẹyin ti wọn lo oogun alagbara tan.
“Ba a ṣe n sọrọ yii, ọrẹ wa ti ṣalaisi. Ileewosan UCH la gbe ọmọbinrin yẹn lọ, oun naa pada ku siọsibitu ọhun “.